Ijọba Kwara sọrọ lori oku maalu tawọn alapata n ta faraalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 24, 2024

Ijọba Kwara sọrọ lori oku maalu tawọn alapata n ta faraalu


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti gbẹsẹ le maalu nla to ku danu, eyi ti wọn lawọn alapata fẹẹ ta fawọn araalu lati jẹ.

Odo Ẹran ti wọn n pe ni Akerebiata, to wa niluu Ilọrin ni iṣẹlẹ ọhun ti waye gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Akọwe agba nileeṣẹ eto agbẹ ati ọgbin, Arabinrin Funkẹ Ṣokọya to fi iroyin ọhun lede sọ pe eto ilera araalu jẹ wọn logun pupọ, fun idi eyi wọn ni lati daabo bo jijẹ iru ẹran abami bẹẹ.

Ṣokọya ni ẹran to ku funra rẹ, tabi ku latari aisi itọju fun lewu pupọ.

O wa rawọ ẹbẹ s'awọn ọmọ ẹgbẹ alapata ni odo Ẹran naa lati dẹkun tita oku maalu fun araalu lati jẹ, nitori ohun ti ko dara ni.

Bakan naa ni Arabinrin Funkẹ Ṣokọya gba awọn agbẹ to n sin maalu, ati awọn alapata lamọran lati ṣadinku ba awọn maalu ti wọn n sin, lati le maa mojuto wọn daadaa, ki wọn ma ba a padanu wọn.

Ẹwẹ, alakoso agba fun ohun ọsin ni ileeṣẹ naa, Dokita Abdullateef Salman Olugbọn rọ awọn alapata lati maa ri daju pe awọn ẹran ti wọn wa ni ilera pipe ni wọn n pa fun tita.

O jẹ ko di mimọ pe loorekoore ni ijọba yoo maa ṣagbekalẹ eto idanilẹkọọ fun wọn lati tubọ mu idagbasoke ba iṣẹ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI