Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe ohun ṣetan lati pin Kẹkẹ Maruwa to n lo ina ẹlẹntiriiki fawọn araalu lati fi mu irọrun ba igbokegbodo ọkọ.
Awọn Kẹkẹ Maruwa naa ti ko din ni ẹgbẹrun marun-un ni ijọba sọ pe ohun yoo pin fun gbogbo awọn ti wọn mọ nipa rẹ daadaa.
Eyi ni ijọba sọ pe yoo mu adinku ba bi awọn eeyan ṣe n lọ lati to fun epo rọbii lawọn ile epo kaakiri ipinlẹ naa.
Bakan naa ni ijọba tun sọ pe awọn Kẹkẹ Maruwa naa ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu ọwọngogo epo rọbii.
Ọjọ Ẹti, Furaide to kọja yii ni ijọba Kwara sọrọ naa nibi idanilẹkọọ ti ipade awọn alẹnulọrọ nipa iṣẹ Kẹkẹ Maruwa, iyẹn Electric Tricycles Acquisition Scheme to waye niluu Ilọrin .
Alakoso agba fun ileeṣẹ EV Mass Transit Solutions, James Clinton, jẹ ko di mimọ pe ẹgbẹrun marun-un Kẹkẹ Maruwa lawọn yoo ko fun Kwara lati mu irọrun ba igbokegbodo ọkọ.
Clinton sọ pe ẹẹdẹgbẹta Kẹkẹ Maruwa lawọn yoo kọkọ ko kalẹ lati fi ṣe idanwo niluu Ilọrin, ko to di pe wọn pin awọn yooku s'awọn ilu miran nipinlẹ Kwara.
Alaga ẹgbẹ awọn oni Kẹkẹ Maruwa, Tricycle Owners Association of Nigeria (TOAN), nipinlẹ Kwara, Saliu Giddado fi ọkan awọn alakoso ileeṣẹ EV Mass Transit Solutions balẹ wi pe wọn yoo ri owo wọn pada laipẹ.
Giddado ni oun jẹri gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn gẹgẹ bii olotitọ eeyan, ti wọn yoo si ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe wọn n tete da owo naa pada.
No comments:
Post a Comment