Ijọba Kwara bẹrẹ dida ọda ikẹyin si opopona Post Office, Ọja Ọba si Ẹmir - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 19, 2024

Ijọba Kwara bẹrẹ dida ọda ikẹyin si opopona Post Office, Ọja Ọba si Ẹmir


Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, awọn agbaṣẹṣe ti bẹrẹ sii da ọda to kẹyin si opopona Post Office, Ọja Ọba titi de Emir niluu Ilọrin, iyẹn nibi ti akanṣe iṣẹ ti n lọ lọwọ.

Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ agba pataki fun gomina lori eto iroyin igbalode, Ọlayinka Fafoluyi fi sita, o ni iṣẹ akanṣe naa ti fẹẹ de ipele ipari.

Fafoluyi ni lara awọn igbesẹ ijọba lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje nipa igbokegbodo ọkọ ti ko labawọn ni atunṣe to n lọ lọwọ naa.


Siwaju sii lo fi da awọn araalu loju pe opopona alalopẹ ni ijọba n ṣe kaakiri ipinlẹ naa, pẹlu awọn agbaṣẹṣe to kaju oṣuwọn.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI