Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti da bọọsi ọfẹ pada fawọn araalu, lati mu ki igbokegbodo ọkọ lọ nirọrun fun wọn.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti ijọba Kwara yoo maa ṣagbekalẹ eto ọkọ ọfẹ lati maa fi gbe awọn eeyan kaakiri ipinlẹ Kwara, paapaa latigba ti afikun owo ori epo rọbii ti bẹrẹ.
Ninu agbekalẹ ati ilana ti ileeṣẹ to n ri sọrọ igbokegbodo ọkọ fi sita, wọn ni awọn bọọsi naa yoo maa ko awọn eeyan lati agbegbe Post Office si Tanke, Unilorin, Ọja, Ẹyẹnkọrin, Amayo, Mandate, Oyun, UITH ati Okeose, to fi mọ awọn agbegbe miran.
Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina AbdulRazaq lori eto iroyin, Ọlayinka Fafoluyi gbe jade, o ni fun irọrun araalu ni agbekalẹ naa wa fun, paapaa fun awọn akẹkọọ ati oṣiṣẹ ijọba.
No comments:
Post a Comment