Ijọba Kwara ati awọn alakoso fasiti Al-Hikmah tọwọ bọwe adehun lori idasilẹ ọsibitu awọn olukọni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 17, 2024

Ijọba Kwara ati awọn alakoso fasiti Al-Hikmah tọwọ bọwe adehun lori idasilẹ ọsibitu awọn olukọni


Lojuna lati mu ki imọ ijinlẹ nipa eto ilera dagba soke sii, pẹlu bi eto ilera araalu ṣe jẹ ijọba logun, ijọba ipinlẹ Kwara ti tọwọ bọwe adehun pẹlu awọn alakoso fasiti Al-Hikmah lori idasilẹ ọsibitu awọn olukọni.

Ọsibitu awọn olukọni naa ni wọn pe ni Al-Hikmah Teaching Hospital ti yoo wa ni Sobi Specialist Hospital, Ilọrin. 

Titọwọ bọwe adehun naa lo waye ni yara pajawiri (EOC) ti ileeṣẹ to n ri seto ilera lonii, Ọjọbọ, Tọside.

Ọna lati jẹ ki ajọṣepọ wa laarin ileeṣẹ aladani ati ijọba, eyi ti wọn n pe ni Public Private Partnership, lati mu imugbooro ba eto ilera ati imọ ẹkọ giga nipinlẹ naa.

Nigba to n sọrọ, Kọmiṣanna feto ilera, Dokita Amina Ahmed El-Imam, ṣapejuwe ipade naa gẹgẹ bi eyi ti wọn ti n foju sọna fun tipẹ, to si loun nigbagbọ pe yoo so eso rere.

O ni ijọba ipinlẹ naa labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fi ara jin fun eto ilera to ye kooro fun awọn araalu, ati lati rii daju pe eto ẹkọ to yanranti wa fawọn eeyan.

O fi kun ọrọ rẹ pe iwe adehun naa jẹ afihan ifarajin wọn fun iṣẹ idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ Kwara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI