Alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited kaakiri agbaye, Aarẹ Adetọla Emmanuelking ti jẹ ko di mimọ pe igbelarugẹ aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba jẹ oun logun pupọ.
Aarẹ EmmanuelKing sọ pe ko si nnkan to le da oun duro, tabi di oun lọwọ lati maa gbaruku ti gbogbo ohun to ba ti nii ṣe pẹlu iṣẹṣe ilẹ Yoruba jakejado.
Nibi abẹwo ti Aarẹ EmmanuelKing pẹlu awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ bii alakoso agba, Arabinrin Adenikẹ Ajọbọ ati awọn yooku ṣe lọ si aafin Ọjaja keji laipẹ yii ni wọn ti jẹ ko di mimọ.
Abẹwo ọhun ni wọn lọ fi ki kabiyesi fun ayẹyẹ aadọta ọdun loke eepẹ.
Aarẹ Adetọla EmmanuelKing gbe oriyin fun Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Enitan Ogunwusi lori ipa rere to n ko lati mu iṣọkan ati alaafia jọba láàrin awọn ọmọ Yoruba lapapọ.
Siwaju sii ninu ọrọ rẹ, Aarẹ EmmanuelKing sọ pe nipa didaabo bo aṣa ati iṣe lo n fi wọn han gẹgẹ bi ọmọ Yoruba, to si lawọn yoo ma ṣe iranlọwọ to ba yẹ lati tubọ gbe ilẹ Yoruba larugẹ.
No comments:
Post a Comment