Gomina AbdulRazaq fi ọgọrun miliọnu naira ta awọn to ṣagbako ijamba ori omi ni Kaiama lọrẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 10, 2024

Gomina AbdulRazaq fi ọgọrun miliọnu naira ta awọn to ṣagbako ijamba ori omi ni Kaiama lọrẹ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti kede ọgọrun kan naira gẹgẹ bi owo iranwọ fun awọn to fara kaasa ninu ijamba ori omi ni Kaiama.

Awọn eeyan to to igba la gbọ pe wọn ni ijamba ninu ọkọ oju omi ọhun lati ijọba ibilẹ Kaiama.

Oni, Ọjọbọ ni gomina kede owo naa lasiko abẹwo to ṣe lọ si aafin Emir tilu Kaiama, Alaaji Omar Mu’azu (Kiyaru IV). 

Nibi abẹwo ọhun ni gomina ti ṣalaye oe ibanujẹ ọkan ni iṣẹlẹ ọhun jẹ fun ipinlẹ Kwara, paapaa ijọba ibilẹ Kaiama.

Bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ pe iṣẹlẹ ijamba naa tun ti jẹ ko di mimọ pe ayẹwo ori omi, paapaa ipo ti odo wa nilo ni gbogbo igba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI