Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo ti buwọlu Ọba Joel Ọlaniyi Ọyatoye Titiloye gẹgẹ bi Oloro tiluu Oro ni ipele keji ọba.
Ninu atẹjade ti kọmiṣanna feto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ Abdullahi Abubakar Bata fi sita, o ni ipele keji ọba ni Oloro tuntun naa yoo wa ninọba ibilẹ Irẹpọdun.
Yatọ si eyi, o tun jẹ ko di mimọ pe gomina tun ti buwọlu Ọba Adebayọ Ọlanrewaju Ismail gẹgẹ bii Gbamoyin tiluu Jimba Ọja.
Gbamoyin yoo wa nipele kẹrin awọn ọba alaye.
No comments:
Post a Comment