Gbogbo awọn to fara kaasa ninu ijamba ọkọ oju omi lo maa jẹ anfaani iranwọ ijọba - Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, October 5, 2024

Gbogbo awọn to fara kaasa ninu ijamba ọkọ oju omi lo maa jẹ anfaani iranwọ ijọba - Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara


Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara, Ọnarebu Yakubu Danladi-Salihu ti ṣeleri pe gbogbo awọn ara abule Gbajigbo to fara kaasa ninu ijamba ọkọ oju omi ni wọn yoo jẹ anfaani eto iranwọ lati ọdọ ijọba ipinlẹ naa.

Ọnarebu Yakubu Danladi-Salihu sọ eyi di mimọ lasiko abẹwo to ṣe lọ si abule Gbajigbo lati ba awọn ara agbegbe naa kẹdun fun ti ijamba ọkọ oju omi to waye, eyi to gbẹmi ọpọ eeyan.

Danladi-Salihu lewaju igbimọ ijoba lọ si abule naa fun abẹwo ibanikẹdun.


Olori ile igbimọ aṣofin naa sọ pe iṣẹlẹ ọhun mu ki ọkan gomina wọn gbọgbẹ gidi pẹlu ibanujẹ, to si ni yoo maa wa ninu iranti ni gbogbo igba.

Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo ran wọn lati wa ṣe abẹwo ibanikẹdun ọhun, lati le mu gbogbo ilu lọkan le pẹlu idaniloju nipa iranwọ ti ijọba yoo ṣe fun awọn to fara kaasa ati mọlẹbi wọn.

Emir ilu Kaiama, Alaaji Muazu Shehu Omar Bagidi Kiyaru kẹrin dupẹ gidigidi lọwọ igbimọ naa, paapaa ijọba Kwara fun akitiyan ati igbiyanju lori iṣẹlẹ ijamba naa.


Lara awọn to tun wa ni ninu ikọ ọhun ni Ọnarebu Saidu Baba; Ọnarebu Abdullah Halidu Danbaba; Ọnarebu. Muhamma Baba Salihu; Ọnarebu Abdullah Bata; Kọmiṣanna feto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Ọnarebu Abdullah Danladi; alaga ijọba ibilẹ Kaiama, Ọnarebu Isa Jibril.

Awọn miran ni alaga ijọba ibilẹ Baruten Alaaji Umar Danladi Shero; alaga ileeṣẹ to n ri sọrọ ijọba ibilẹ, Ọnarebu Sadiq Buhari; oludamọran fun gomina lori ọrọ araalu ati awọn miran.

Bakan naa ni wọn tun lọ ṣe abẹwo si Baale agbegbe Gbajigbo, Alaaji Ibrahim Usman.






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI