Ẹtọ kan naa ni ọmọbinrin ati omokunrin ni, ẹ dẹkun ẹyamẹya - Gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 17, 2024

Ẹtọ kan naa ni ọmọbinrin ati omokunrin ni, ẹ dẹkun ẹyamẹya - Gomina AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti rọ awọn eeyan lati dẹkun iwa ẹlẹyamẹya laarin awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin, ati pe ẹtọ kan naa ni wọn jọ ni lawujọ.

Bakan naa ni gomina tun fidi ileri rẹ mulẹ pe ijọba oun yoo tubọ maa ṣe ironilagbara fun awọn ọmọbinrin loorekoore.

Ọjọbọ, Tọside ọsẹ yii ni Gomina AbdulRazaq sọrọ naa jade nibi ayajọ ọjọ awọn ọmọbinrin lagbaye, ti ọdun 2024, eyi ti wọn ṣe ni gbọngan Stella Ọbasanjọ to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

Ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ awọn obinrin lo ṣagbekalẹ eto ọhun ti wọn pe akori rẹ ni "afojusun ọmọbinrin fun ọjọ iwaju" (Girl Vision for the Future).

Gomina AbdulRazaq nigba to n sọrọ lati ẹnu kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ naa, Dokita Amina Ahmed El-Imam jẹ ko di mimọ pe ofin ẹtọ ọmọde, ati iwa ipa lodi si eeyan (Child's Rights Law, Violence Against Persons and Prohibition (VAPP)), to fi mọ Gender Composition Law, ati awọn miran ṣi n fẹsẹ mulẹ.

"Ofin naa rii daju pe awọn ọmọ ni eto ẹkọ to ye kooro, ati pe wọn ni aabo to pe ye si oniruuru iwa ipa to le fẹẹ dide lodi si wọn," o ṣalaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI