Elerin tiluu Erin-Ile nipinlẹ Kwara, Ọba Adesoye Adebọwale Jimọh ti gbọpa aṣẹ ati iwe ẹri.
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo gbe ọpa aṣẹ ati iwe ẹri le Ọba Adesoye Jimọh lọwọ lonii, ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2024.
Gbọngan nla ti Big Council Chamber to wa nile ijọba to wa niluu Ilọrin ni eto ọhun ti waye.
Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti gba ọba tuntun naa lamọran lati lo ipi rẹ lati fi mu iṣọkan, ifẹ, alaafia ati idagbasoke ba ilu to jọba le lori fun ilọsiwaju ipinlẹ Kwara lapapọ.
No comments:
Post a Comment