Bi Gomina AbdulRazaq ṣe mu eto ilera lọkunkundun jẹ ohun iwuri nla - Emir Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 9, 2024

Bi Gomina AbdulRazaq ṣe mu eto ilera lọkunkundun jẹ ohun iwuri nla - Emir Ilọrin


Emir ilu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Zulu-Gambari ti gbe oṣuba kare fun Gomin AbdulRahman AbdulRazaq lori bo ti ṣe mu eto ilera lọkunkundun, fun awọn ara ipinlẹ Kwara.

Ọmọwe Zulu-Gambari lo sọ eyi nibi ifilọlẹ ipolongo eto ilera ti wọn pe ni Project 10 Million, eyi ti ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ilera ni Kwara ṣagbekalẹ rẹ ni aafin Emir ilu Ilọrin.

Nigba to n ṣiṣọ loju eto ọhun, Dọkita Amina Ahmẹd El-Imam to jẹ kọmiṣanna feto ilera sọ fawọn akọroyin pe eto naa ni lati ṣe eto ayẹwo to peye fun awọn araalu, lati le bọ kuro ninu oniruuru ailera to le maa ba wọn finra.
 
O ni titete ṣawari aisan to ba wa lara ṣe pataki pupọ, paapaa julọ aisan ẹjẹ riru ati itọ ṣuga, to sọ pe ko dara rara, nitori to le ṣe akoba fun agọ ara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI