Ayẹwo ọfẹ fun itọju ẹjẹ riru ati itọ-ṣuga bẹrẹ ni pẹrẹu ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, October 24, 2024

Ayẹwo ọfẹ fun itọju ẹjẹ riru ati itọ-ṣuga bẹrẹ ni pẹrẹu ni Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣagbekalẹ eto ayẹwo ọfẹ fun itọju ẹjẹ riru ati itọ-ṣuga fawọn araalu lojuna lati mu adinku ba iku ojiji.

Kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa nipinlẹ Kwara ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ki wọn gbe eto ọhun lọ.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 2024 ni yoo bẹrẹ ni pẹrẹu 

Gbogbo eeyan ni yoo ni anfaani lati lọ ṣayẹwo, lati mọ boya wọn ni aisan itọ ṣuga tabi ẹjẹ riru lara, ki wọn le tete lọ fun itọju.

Ọsẹ kan gbako ni eto ọhun yoo fi waye bẹrẹ lati ọjọ Aje, titi di ọjọ Aiku, ọjọ kẹta, oṣu kọkanla, ọdun 2024.

Kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ naa, Dokita Amina Ahmed El-Imam lasiko to n ṣalaye nibi ipade oniroyin ni ọfiisi rẹ lonii, o jẹ ko di mimọ pe agbekalẹ Gomina AbdulRazaq ni.

Bẹẹ lo ni gomina fẹ ki eto ilera ọfẹ naa dele-doko.

El-Imam fi kun ọrọ rẹ pe ipolongo eto ilera atẹyinwa ti ṣe iranwọ pupọ fun araalu, pẹlu bo ṣe ni awọn eeyan jẹ anfaani lati wa ni ilera pipe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI