Aye o! Wọn yinbọn pa oludije sipo kansẹlọ nile paraga l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

Saturday, October 12, 2024

demo-image

Aye o! Wọn yinbọn pa oludije sipo kansẹlọ nile paraga l'Abẹokuta

IMG_ORG_1728740686811

Niṣe lọrọ di boolọ o yago lọna lonii, ọjọ Abamẹta nigba ti awọn kan tẹnikẹni ko mọ yinbọn pa ọkan lara awọn oludije sipo kansẹlọ niluu Abẹokuta.

Adeleke Adeyinka ni orukọ ọmọkunrin naa, ti wọn lo n dije du ipo kansẹlọ ni wọọdu kẹẹdogun, ijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta.

Ibi ti wọn lo ti n ṣe faaji pẹlu awọn ọrẹ rẹ ni Oke-Ilewo ni wọn ti yinbọn fun un.

Adeyinka gbajumọ daadaa lagbegbe ti wọn n n pe ni Jide Jones, Oke-Ilewo.

Ọdọ Peju oni Paraga ti wọn n pe ni Schuchies la gbọ pe o ti n ṣe faaji ki iṣẹlẹ ọhun to waye.

IMG_ORG_1728741003101

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI

Contact Form

Name

Email *

Message *