Ayajọ olukọ lagbaye: Gomina AbdulRazaq kede ọjọ Aje gẹgẹ bi ọjọ isinmi fawọn oṣiṣẹ Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, October 6, 2024

Ayajọ olukọ lagbaye: Gomina AbdulRazaq kede ọjọ Aje gẹgẹ bi ọjọ isinmi fawọn oṣiṣẹ Kwara


Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ipinlẹ Kwara ti kede ọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu kẹwaa gẹgẹ bi ọjọ isinmi fawọn oṣiṣẹ.

Ikede yii ni lati saami ayẹyẹ ayajọ ọjọ awọn olukọ kaakiri agbaye, eyi to waye lọjọ Abamẹta to kọja.

Nigba to n kede isinmi naa, Gomina AbdulRazaq gbe oṣuba kare fun gbogbo oṣiṣẹ lagbaye, paapaa nipinlẹ Kwara fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lati ṣatọna awọn ogo ọjọ iwaju orileede Naijiria.

Gomina AbdulRazaq sọ pe iṣẹ ribiribi manigbagbe ni awọn olukọ n ṣe nipa idagbasoke orileede.
 
Ninu atẹjade ti ijọba fi sita lati ileeṣẹ to n bojuto eto ẹkọ nipinlẹ naa, eyi ti Hajia Sa'adatu Modibbo Kawu buwọ lu lọjọ Aiku oni, o ni gbogbo olukọ to wa nile ẹkọ ijọba ati aladani ni yoo jẹ anfaani ọlude naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI