AbdulRazaq kẹdun iku awọn to kagbako ninu ijamba ori omi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 2, 2024

AbdulRazaq kẹdun iku awọn to kagbako ninu ijamba ori omi


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba awọn ara agbegbe Gwajibo Mudi to wa nijọba ibilẹ Kaiama kẹdun, lori bi wọn ṣe kagbako ninu ijamba ọkọ oju omi to waye nipinlẹ Kano.
 
Abule kan ti wọn pe ni Gwajibo Mudi niṣẹlẹ ọhun ti waye, nibi ti awọn eeyan ti ko din ni igba lati agbegbe ọhun ti fara kaasa.

Abule Gwajibo la gbọ pe ọkọ oju omi naa ti kuro, to si n lọ fun ayẹyẹ Maulid nabbiy.
 
Ohun ti awọn alakoso lagbegbe naa sọ ni pe awọn mọkanlelọgbọn ni wọn ṣi ri yọ jade ninu gbogbo wọn.
 
Nigba to n kẹdun, Gomina AbdulRazaq sọ pe ẹdun ọkan nla lo jẹ foun lati gbọ nipa ohun ṣẹlẹ yii.
 
O ba Ẹmir, Alaaji Omar Mu’azu Shehu ilu Gwajibo kẹdun, o si mu gbogbo araalu lọkan le, pẹlu ileri wi pe oun yoo ṣe iranwọ to ba yẹ fawọn to fara kaasa, paapaa awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn ninu ijamba naa.
 
Bakan naa lo dari awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, SEMA lati lọ ṣe iranwọ fawọn eeyan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI