AbdulRazaq kẹdun iku Alagba Ndakene, agba oloṣelu ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

Tuesday, October 15, 2024

demo-image

AbdulRazaq kẹdun iku Alagba Ndakene, agba oloṣelu ni Kwara

IMG_ORG_1728980504641

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti kẹdun iku agba oloṣelu nni, Alaaji  Abubakar Ndakene, ẹni ti jade laye laipẹ yii.

Alaaji Ndakene to jẹ Marafan Shonga lo dagbere faye lẹyin aisan rampẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye fi sita, AbdulRazaq ni afanu nla ni iku baba naa jẹ fun ipinlẹ Kwara, paapaa awọn ara ijọba ibilẹ Edu.

Bakan naa lo gbe oriyin fun ipa rere ti oloogbe naa ko nigba aye ẹ si ipinlẹ Kwara ati orileede Naijiria lapapọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI

Contact Form

Name

Email *

Message *