AbdulRazaq buwọ lu ajagunfẹyinti Ademọla Lawal gẹgẹ bii alaga ajọ ETF - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, October 9, 2024

AbdulRazaq buwọ lu ajagunfẹyinti Ademọla Lawal gẹgẹ bii alaga ajọ ETF


Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ti ipinlẹ Kwara ti buwọ lu Colonel Abdulwahab Ademọla Lawal gẹgẹ bi alaga ajọ to n ri sọrọ iṣuna eto ẹkọ, iyẹn 'Kwara State Education Trust Fund (ETF)'.

Lawal ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi ologun nilẹ Naijiria fun ọdun mejilelogun, ko to fẹyinti lọdun 1995. Ọpọ ẹka lọkunrin naa ti ṣiṣẹ ninu iṣẹ ologun.

Bakan naa lo tun ṣiṣẹ papọ pẹlu ajọ United Nations Peacekeeping Operations ni Iran-Iraq military Observer Group lọdun 1988 si 1999, to si tun wa lara igbimọ ECOMOG laaarin ọdun 1992 si 1994.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI