Wolii Ọladele Genesis wọ ilu Abẹokuta fun akanṣe iṣoji ọlọjọ mẹta lara-ọtọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 30, 2024

Wolii Ọladele Genesis wọ ilu Abẹokuta fun akanṣe iṣoji ọlọjọ mẹta lara-ọtọ


Gbajugbaja Wolii nni, Israel Ọladele Ogundipẹ to jẹ alaṣẹ ati oludari ijọ Sẹlẹ ti Genesis Global to wa niluu Ekoo ti sọ pe Ọlọrun lo fun oun ni itọni lati gbe iṣọji ọlọjọ mẹta gbako kalẹ nipinlẹ Ogun, paapaa ilu Abẹokuta.
 
Wolii Genesis Global sọ pe iṣọji ọhun kii ṣe fun awọn ọmọ ijọ Sẹlẹ nikan, bi ko ṣe fun awọn ọmọ ijọ alaṣọ funfun ati alaṣọ ara kaakiri agbaye.
 

Ọjọ kinni si ọjọ kẹta, oṣu kẹwaa ọdun 2024 ti a wa ninu ẹ yi ni iṣọji ọhun ti wọn pe akọri rẹ ni 'Abẹokuta Prophetic Invasion' yoo waye, iyẹn ọjọ Iṣẹgun tii ṣe Tusidee, titi di Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii.
 
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ laipẹ yii, Wolii Israel Ogundipẹ ṣalaye pe igba kọkọ ree ti oun yoo gbe iṣoji kalẹ niluu Abẹokuta, paapaa ni ilu ti kii ṣe ipinlẹ Eko.
 

Ogbontarigi Wolii ti Ọlọrun n gba ọwọ rẹ ṣiṣẹ itusilẹ nipa iṣẹ ami ati ororo atokewa jẹ ko di mimọ pe bi isọji ọhun ṣe wa fun Kristiẹni naa lo wa fun Musulumi.
 
Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe eto aabo eemi ati dukia awọn olukopa ti wa nilẹ nitori pe oriṣiriṣi ileeṣẹ eleto aabo ni wọn ti fiwe pe lawọn ọjọ naa.
 
Gbagede inu ọgba Ọba Adelẹyẹ to wa ni Ori Omi, Oke Ṣokori ni isọji ọhun yoo ti waye, bẹrẹ lati agogo mẹrin irọlẹ ojoojumọ.


‘Eto ọlọjọ mẹta ni, Ọlọrun lo fun mi ni itọni lati gbe isọji ọhun kalẹ fun itusilẹ ati irapada. Ọmọ bibi ilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni mi. Eto aabo to gbookan ti wa nilẹ, nitori pe kii ṣe fun ẹlẹsin Kristiẹni nikan.
 
‘Iṣoji ọhun wa fun ipinlẹ Ogun ati awọn ipinlẹ to tun sunmọ-ọn”, Wolii Genesis jẹ ko di mimọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI