Wahala de! Gbenga Makanjuọla fẹgbẹ oṣelu PDP silẹ ni Kwara, o tun ko awọn ọmọ ẹyin rẹ wọ APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 19, 2024

Wahala de! Gbenga Makanjuọla fẹgbẹ oṣelu PDP silẹ ni Kwara, o tun ko awọn ọmọ ẹyin rẹ wọ APC


Idarudapọ lo tun wọnu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Kwara pẹlu bi gbajugbaja oloṣelu nni, Gbenga Makanjuọla ṣe fẹgbẹ naa silẹ, to si ba ẹgbẹ miran lọ.
 
Ko si nnkan meji to mu ki iṣẹlẹ ọhun jẹ kayeefi bi ko ṣe bi Makanjuọla to tun jẹ aṣoju-ṣofin to n ṣoju ẹkun Isin, Oke-Ero, Irẹpọdun ati Ekiti nile igbimọ aṣofin kekere niluu Abuja tun ṣe ko awọn ọmọ ẹyin rẹ wọnu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.

Iroyin to tẹ wa lọwọ jẹ ko di mimọ pe nitori eto idibo ijọba ibilẹ to n bọ lọna lopin ọsẹ yii, lo fa a ti ọkunrin naa fi darapọ mọ APC.
 
Bi ẹ ko ba gbagbe, lọgbọn ọjọ, oṣu keje  ni Makanjuọla kede sita wi pe oun ko ba ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe papọ mọ, to si loun ti fẹgbẹ naa silẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI