Saraki ko lẹnu ọrọ lori eto idibo ijọba ibilẹ to waye ni Kwara - Ijọba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 27, 2024

Saraki ko lẹnu ọrọ lori eto idibo ijọba ibilẹ to waye ni Kwara - Ijọba


Ijọba Kwara ti sọ pe aarẹ ile igbimọ aṣofin agba lorileede Naijiria tẹlẹ, Sẹnetọ Bukọla Saraki ko lẹnu ọrọ lati sọrọ lori abajade eto idibo ijọba ibilẹ to waye kọja, nibi ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ti jawe olubori.

Ijọba sọ pe gbogbo ọna ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti Saraki n ṣakoso rẹ ni Kwara n wa lati dabaru eto idibo ijọba ibilẹ to waye kọja nipa awọn iwa jagidijagan.

Wọn ni gbogbo ijọba ti ṣe daadaa fun araalu, eyi to jẹ ki awọn eeyan nigbagbọ ninu ẹgbẹ APC lati dibo fun gbogbo awọn iludije sipo alaga kansu ati kansẹlọ wọn.

Ninu atẹjade ti kọmiṣanna feto ikansira-ẹni, Arabinrin Bọla olukoju fi sita, o ni awawi lasan ni saraki n wa, nigba ti idibo ọhun ya a lẹnu lori ọna ti awọn araalu fi dibo fun APC.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI