PDP jawe lọ gbele rẹ fun Dino Melaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 13, 2024

PDP jawe lọ gbele rẹ fun Dino Melaye


Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Kogi ti jawe lọ gbele rẹ fun Sẹnetọ Dino Melaye.
 
Awọn alakoso ẹgbẹ naa ni wọọdi kinni, ẹkun Ayetoro Gbede ni wọn paṣẹ pe awọn da Melaye duro lori ẹsun agabagebe ẹgbẹ.
 
Lara awọn ẹsun miran ti wọn tun fi kan Melaye ni bo ṣe kọ lati yọju si ipe ti wọn pe e, lati wa dahun awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
 
Nibi ipade igbimọ ẹgbẹ naa ti wọn ṣe, ni wọn ti gbe ipinnu kalẹ, iyẹn ni wọọ kinni, ẹkun Aiyetoro/Luagba loni ọjọ Ẹti, ni wọn ti sọ pe Melaye kọ eti ikun si bi igbimọ amuṣẹṣe ṣe ranṣẹ pe e.
 
Alaga ẹgbẹ ni wọọdu naa, Abayọmi Osamika ati akọwe wọn, Yodson Dayo ni wọn jọ buwọ lu iwe ti wọn fi da Melaye duro.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI