Ọ̀wọ́ngógó: Ìjọba Kwara kó ọkọ̀ rẹpẹtẹ síta láti gbé aráàlú lọ́fẹ̀ẹ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 5, 2024

Ọ̀wọ́ngógó: Ìjọba Kwara kó ọkọ̀ rẹpẹtẹ síta láti gbé aráàlú lọ́fẹ̀ẹ́


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ko ọpọlọpọ ọkọ sita lati gbe araalu lọ sibi ti wọn ba n fẹ, lati le mu irọrun ba awọn eeyan.

Ijọba Kwara sọ pe lati le mu inu araalu dun nipa igbokegbodo ọkọ, awọn nilo lati wa ọna abayọ si iṣoro ọwọngogo epo.

Kaakiri agbegbe to wa nipinlẹ naa ni gomina ti paṣẹ pe ki awọn ọkọ ọhun to jẹ bọọsi maa gbe awọn eeyan lai san owo kankan.

Anfaani yii la gbọ pe yoo tun wulo pupọ fun awọn to n wa iṣẹ SUBEB, nitori pe yoo jẹ irọrun fun wọn.

Siwaju ni gomina rọ araalu ati awọn awakọ lati ṣe suuru lori epo rọbii to lọ soke, ati pe awọn alẹnulọtọ nijọba ti n wa ọna abayọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI