Ọ̀wọ́ngógó: Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn kéde ìsinmi ọjọ́ méjì láàárín ọ̀sẹ̀ kan fàwọn òṣìṣẹ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 12, 2024

Ọ̀wọ́ngógó: Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn kéde ìsinmi ọjọ́ méjì láàárín ọ̀sẹ̀ kan fàwọn òṣìṣẹ́


Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun ti kede isinmi ọlọjọ meji fun awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa.
 
Gomina Dapọ Abiọdun buwọ lu eyi lati mu idẹrun ba awọn oṣiṣẹ lori bi owo jaala epo bẹntiroolu ṣe lọ soke.
 
Ninu atẹjade ti olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa, Kẹhinde Ọnasanya fi sita laipẹ yii.
 
o pe awọn oṣiṣẹ ni ipele kinni titi di ipele kẹrinla yoo maa lọ fun isinmi ọlọjọ meji laarin ọsẹ kan, nigba ti awọn oṣiṣẹ lati ipele kẹẹdogun si ipele kẹtadinlogun yoo maa lọ isinmi ọlọjọ kan laarin ọsẹ kan.
 
Ọnasanya sọ pe bayii ni gomina ṣe buwọ lu eto iṣẹ fawọn oṣiṣẹ ijọba lasiko ọwọngogo epo bẹntiroolu lasiko yii, fun idẹrun ati igbayegbadun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI