Ọ̀wọ́ngógó Epo Rọ̀bìì: Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Ilorin Emirate rọ aráàlú láti ṣe sùúrù - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 5, 2024

Ọ̀wọ́ngógó Epo Rọ̀bìì: Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Ilorin Emirate rọ aráàlú láti ṣe sùúrù


Ẹgbẹ ọdọ Ilọrin nni, ti wọn pe ni Ilorin Emirate Youth Progressive Association ti rawọ ẹbẹ si araalu lati ṣe suuru lori ọwọngogo epo rọbii to wa nita.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa gbe jade lonii, Ọjọbọ, Tọside ni wọn ti rawọ ẹbẹ si araalu lati gba alaafia laaye, dipo ki wọn da wahala silẹ.

Atẹjade ọhun ti akọwe iroyin wọn, Abdulrasheed AbdulGaniy buwọ lu ninu Ilọrin, ipinlẹ Kwara lo ti sọ pe ijọba apapọ orileede Naijiria ti n gbe igbesẹ ti yoo mu irọrun ba araalu lori owo jaala epo to lọ soke.

“A n'igbagbọ pe awọn ọrọ to n lọ kaakiri lori owo jaala epo rọbii to kuro ni N617 naira lọ si N877 naira ti de ọdọ ijọba apapọ, ti yoo si gbe igbesẹ to tọ laipẹ fun anfaani araalu.”

“Lori eyi la fẹẹ bẹ gbogbo eeyan lati ṣe suuru nigba ti ijọba apapọ yoo ṣe ohun to tọ niwọn igba ti owo jaala epo to lọ soke kii ṣe ohun to rọ araalu lọrun.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI