Ọwọ Amọtẹkun tẹ Yakubu to fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹwaa l'Ekiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 19, 2024

Ọwọ Amọtẹkun tẹ Yakubu to fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹwaa l'Ekiti


Ọwọ ileeṣẹ eleto aabo ibilẹ nni, Amọtẹkun, ẹka tipinlẹ Ekiti ti tẹ gendekunrin, ẹni ọdun mejilelọgbọn nni, Yakubu Maji ti wọn lo fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹwaa.
 
Ninu atẹjade ti alokoso eto iroyin fun ileeṣẹ Amọtẹkun nipinlẹ Ekiti, Adelẹyẹ Abiọdun Adewale fi sita fawọn akọroyin niluu Ado-Ekiti l'Ọjọbọ, oni, o jẹ ko di mimọ pe ṣikun lọwọ tẹ Yakubu.

Agbegbe Are-Ekiti ni Yakubu, ọmọ bibi ipinlẹ Kogi ọhun n gbe, ati pe awọn oṣiṣẹ Amọtẹkun ti ẹkun ijọba ibilẹ Ifẹdara lo rọwọ to o lọjọ Aje, ọsẹ yii.
 
Siwaju sii ni wọn jẹ ko di mimọ pe igba meji ọtọọtọ ni Yakubu fipa ja ibale ọmọ ọhun to wa lati ilu Okene.
 
Ọmọ naa lasiko to n ṣalaye jẹ ko di mimọ pe asiko ti wọn ran oun niṣẹ ni Yakubu fi ọọdunrun naira tan oun wọnu yara, nibi to ti ja ibale oun.
 
Siwaju sii lo sọ pe niṣe ni Yakubu fi ada dunkoko iku mọ oun bi oun ba fi le tu aṣiri sita
 
Iya ọmọ naa ninu ọrọ to sọ fun Amọtẹkun fi ye wọn pe igba keji ree ti Yakubu yoo fipa ba ọmọ oun laṣepọ.
 
Amọtẹkun ninu atẹjade ọhun fidi rẹ mulẹ pe awọn ti fa Yakubu le awọn ọlọpaa ipinlẹ Ekiti lọwọ lati tẹsiwaju iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI