Ọwá Ọbọ̀kun tìlùú Ìjẹ̀ṣà tẹ́rí-gbaṣọ, làwọn ọlọ́pàá àti ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ bá gba ìṣàkóso ààfin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 12, 2024

Ọwá Ọbọ̀kun tìlùú Ìjẹ̀ṣà tẹ́rí-gbaṣọ, làwọn ọlọ́pàá àti ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ bá gba ìṣàkóso ààfin


Ọwa Ọbọkun tiluu Ijẹṣa, Ọba Adekunle Aromọlaran ti tẹri gbaṣọ lẹni ọdun mẹtadinlaadọrun (87years).

Ọdun kejilelogoji ree ti Ọba Aromọlaran ti wa lori ipo awọn baba-nla rẹ, ko to di pe o dagbere faye.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe ṣalaye, wọn ni o ti ṣe diẹ ti ara kabiyesi ko ti da, ti a si gbọ pe ile iwosan olukọni ti Obafemi Awolowo University Teaching Hospital, to wa niluu Ile-Ifẹ, ipinlẹ Ọṣun ni kabiyesi ti n gba itọju.
 
Ọjọru, Wẹside, ọjọ kọkanla, oṣu kẹsan, ọdun 2024 ni Kabiyesi ki aye pe o digboṣe, gẹgẹ bi awọn to sunmọ aafin ṣe sọ.

Bi iroyin ipapoda kabiyesi ṣe jade sita la gbọ pe ọpọ awọn agbofinro ati ọtẹlẹmuyẹ sare lọ si aafin naa lati duro sibẹ.
 
Owe ni awọn oloye fi n sọrọ lori iku kabiyesi naa.

Lara awọn mọlẹbi to ba awọn akọroyin sọrọ jẹko di mimọ pe niṣe ni wọn n ko awọn ẹru ati dukia kabiyesi jade kuro ni aafin, ti ko si sẹni to le sọ idi rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI