Ọwá Ọbọ̀kun Àdìmúlà, Ọba Gabriel Adékúnlé Aromọlaran kejì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 12, 2024

Ọwá Ọbọ̀kun Àdìmúlà, Ọba Gabriel Adékúnlé Aromọlaran kejì


A tun ki i yin k’aabo si abala K’ADE PẸ LORI l’ọsẹ yii, a si fẹẹ dupẹ lọwọ ẹyin ololufẹ ti ẹ n tẹle wa ni gbogbo igba. Ọlọrun yoo wa pẹlu yin. 
 
Bi e ba pe e n’ilu Ileṣa, ẹ ko ṣisọ, bi ẹ si pe e n’ilu Ijẹṣa, rẹgi lo ṣe. L’ọsẹ yii, ilu Ileṣa n’ipinlẹ Ọṣun la n lọ, Aafin kabiyesi, Ọwa Ọbọkun Adimula, Ọba Gabriel Adekunle Aromọlaran keji to doloogbe lọjọ kọkanla, oṣu kẹsan, ọdun 2024 la n lọ. Ade ti pẹ lori, bẹẹ si ni bata ti pẹ lẹsẹ ko to di pe kabiyesi tẹri gbaṣọ lẹni ọdun mẹtadinlaadọrun. Ọdun mejilelogoji ni kabiyesi lo lori itẹ awọn baba-nla rẹ.

A ko ni i lọ pupọ s’inu itan iṣẹdalẹ ilu Ileṣa ati bi awọn Ijeṣa ṣe bẹrẹ igbesi aye wọn, bo tilẹ jẹ pe diẹ la maa mẹnuba nibẹ, nitori pe abala yii ki i ṣe abala itan ilu. A ko ni ṣai ranti awọn Ọba to ti jẹ tẹlẹ titi de ori Kabiyesi, iyẹn Ọba Gabriel Adekunle Aromọlaran keji.

Ipinlẹ Ọṣun ni ilu ti wọn n pe ni lleṣa wa, o si jẹ ọkan lara awọn ilu ti wọn ni Aafin to ni itan nla. Ọwa Ọbọkun Adimula ni wọn n pe orukọ Ọba wọn.

Okan pataki l’ara awon ilu to wa n’ipinle Osun ni ilu Ilesa, iyen ilu Ijesa wa. Pupo awon ilu ti won si wa n’ipinle naa lo je pe won n pe oruko Ijesa mo won l’ara. Lara won si ni: Erin Ijesa, Ijeda-Ijesa, Ipetu Jesa, Ijebu-Jesa, Ipole Ijesa, Ifewara Ijesa, Iloko Ijesa, Iwara Ijesa, Iperindo Ijesa, Erinmo Ijesa, Iwaraja Ijesa, Erin Ijesa, Ilase Ijesa, Igangan ijesa, Imo Ijesa, Alakowe Ijesa, Osu Ijesa, Epe Ijesa, Omo Ijesa, Iloba Ijesa, Odo Ijesa, Imogbara Ijesa, Eseun Ijesa, Iloo, Owena Ijesa, Ido Ijesa, Ido Oko Ibala Ijesa.

Yato si awon wonyii, a tun ni awon ilu bi i Ibokun, Esa-Oke, Idominasi, Eti Oni, Itaore, Itagunmodi, Itaapa, Ibokun, Inila, Ijinla, Iloo, Idominasi, Ilowa, ati Ibodi to je pe abe Ijesa ni gbogbo won wa. Owa Obokun Adimula si ni Olori oba gbogbo won patapata.

Odun 1300 ni won da ipinle ilu Ijesa sile. Ajibogun Ajaka Owa Obokun Onida Raharaha to je jagunjagun alagbara, eni to je omo-omo Oduwuwa lo da ilu Ijesa sile, sugbon Owulase to je omo omo Ajibogun Ajaka lo fi oruko Ilesa lele. Eyi lo fi je pe bi won se n pe ilu naa ni Ijesa naa ni won tun n pe e ni Ilesa labe akosile ofin.

Lara iran Oba Olofin n’ilu Ile Ife ni Ajibogun Ajaka Owa Obokun. L’ara awon omo, omo-omo ati omo-omo-omo Olofin ni Oba ilu Benin, Oba Oyo, Osemawe tilu Ondo (to je omo omo re obinirn), Alara tilu Ara, Ajero tilu Ijero, Alaye ilu Efon Alaaye, Owore t’ilu Otun, Orangun t’ilu Ila, Aregbajo t’ilu Igbajo ati Owa Ajaka t’ilu Ilesa.

N’igba ti Olofin dagba, ti ojo re ti n di ogbo lo, oju re fo, to je pe won wa gbogbo ona lati je ki oju re la, sugbon ti ko la. Gbogbo igbese ta a gbo pe won gbe lati je ki oju Olofin la lo ja si pabo. Okunrin kan la gbo pe o yoju l’eyin odun bi i meloo ti oju Olofin ti rele, to si so pe bi won ba le ri odo to ni iyo ninu, pelu awon eroja kan, oju Olofin yoo la.

Won ni irin ajo ojo pipe ni eni ti yoo lo wa awon eroja naa wa yoo rin, ti won si ni ona abayo kan soso niyen. Irin ajo yii la gbo pe yoo lewu pupo fun eni to ba lo, sugbon eni to ba ni akikanju gidi nikan ni yoo lo, ti yoo si bo. Bi Olofin se gbo awon oro wonyii, o pe gbogbo awon omo re jo, o si salaye fun gbogbo won, ati pe inu oun yoo dun lati ri eni ti yoo ba oun lo wa awon eroja naa wa.

Ko si eyi to dahun ninu awon omo ati omo omo re. N’igba ti okan lara awon omo omo Olofin ri i pe ko s’eni to le lo ninu gbogbo awon egbon re, o dide lati so pe oun yoo lo. Ajaka l’oruko Omoba naa, won si tun n pe e ni Esinkin. Esinkin yii je oruko kan to je pe eeyan lasan ko le je, se ni ipo Esinkin ko fee yato si ipo Kakanfo. Esinkin yii lo seleri wi pe oun yoo lo wa awon nnkan etutu naa wa.

Bo se lo ti won ko gburo re mo ree. Odun kinni koja, odun si iketa koja to fi mo odun marun-un. N’igba ti won ko gburo re, Olofin ronu pe agba ti n de si oun, oun ko si fe ija l’aarin awon omo ati omo omo re l’ori ogun oun. O pin ogun naa fun won, ko si fi ogun kankan sile fun Esinkin. Bo se pin ogun naa tan ni onikaluku won gba ibi ori da won si lati tedo lo, won ko si ronu nipa Esinkin rara.

L’eyin opolopo odun, lai ronu nipa re mo, Esinkin wole de pelu awon eroja etutu ati omi oniyo lati inu odo. Bi Olofin se lo o, si iyalenu, oju re la. Idi pataki ree ti won fi n pe gbogbo awon omo Ijesa ni Omo Obokun. Idunnu nla lo je fun Olofin, to si wo o pe ki l’oun le se. O wo egbe re, o ri ida kan ti ewe wa lara re nibe. O si mu ida yii fun Ajaka (Esinkin) wi pe ko lo ba awon egbon re jagun, ko si gbo ninu ogun t’oun pin fun won fun ara re. Alara ati Alado ni Olofin ni ki Ajaka lo ba ja lati gba ogun lowo won.

Ida naa ni won fi n pe Ajaka ni Owa Ajaka Onida Raharaha. Opolopo isele lo waye l’eyin eyi, sugbon ju gbogbo re lo, Ajaka di Oba.

Ajibogun Ajaka je Owa Obokun Adimula l’aaarin odun 1150 si odun 1255; Awoka Okile lo je l’eyin re l’aaarin odun 1260 si odun 1358. Obarabara Olokun Esin je l’odun 1360 si odun 1459; Owari je l’aaarin odun 1466 si 1520; Owaluse to so ilu Ilesa l’oruko labe ofin lo je l’aaarin odun 1522 si 1526. Leyin re ni Atakunmosa je l’aaarin odun 1526 s’odun 1560. Ko s’eni to gun ori ipo naa titi odun 1572 ti Oge je, to je l’aaarin odun naa si odun 1587.

Biilayi Arere (Yeyelagagba) je l’aaarin odun 1588 si 1590; Yeyegunrogbo je l’aaarin odun 1590 si 1591; Yeye Ladegba je l’aaarin odun 1646 si 1652; Biiladu kinni-in je l’aaarin odun 1652 si odun 1653; Biiladu keji lo je l’eyin re l’aaarin odun 1653 si odun 1681. Yeyewaji ni won yan l’eyin re l’odun naa, to si je pe odun 1681 naa lo waja. Odun naa gan-an ni won yan Biilaro gege bi Owa Obokun Adimula, to si waja l’odun 1690. Bilayiarere to je Wayero kinni lo je l’eyin re, iyen l’odun 1691 to si je pe odun pere lo lo n’ipo naa. O tun je iyalenu pe bi Wayero kinni se waja l’odun 1692, ti won yan Wayero keji, odun kan pere l’oun naa wo n’ipo, odun 1693 l’oun naa waja.

L’eyin eyi ni won yan Wayero keta, t’oun si je l’aaarin odun 1698 si odun 1712; Biilagbayo lo je l’eyin re, l’odun 1713 si odun 1733; Ori Abejoye je l’odun 1734 si 1749; Biilajagodo Arijelesin je l’odun 1749 si 1771; Biilatutu ‘Otutu bi Osin’ je l’odun 1772 si 1776; Biilasa ‘Asa Ab’odo-Funfun’ je l’odun 1776 si odun 1778; odun 1789 ni Akesan je si odun 1795; Biilajara je l’odun 1796 si odun 1803. Ogbagba je l’odun 1804 si odun 1813; Obara ‘Bilajila’je l’odun 1813 si odun 1828; Odundun lo je l’odun 1828 si odun 1833; Gbegba Aje je l’aaarin odun 1833 si odun 1839.

Won ko ri enikeni fa kale l’awon asiko yii, eyi lo je ki won pinnu lati yan adele oba akoko, iyen Ariyasunle l’odun 1839. Ko pe ti won fi ri Ofokutu, to si je l’aaarin odun 1839 si odun 1853. Bi Ofokutu tun se waja ni won tun pe Ariyasunle lati wa a se adele oba l’eekeji, to si se e wo odun 1858; Aponlese je l’odun 1858 si odun 1867; Alobe je l’odun 1867 si 1868; Agunlejika kinni lo je l’ aaarin odun 1868 si 1869; Oweweniye naa je l’odun 1871 s’odun 1875; 1875 ni Bepolonun je ko o waja l’odun 1893; Alowolodu lo gba ipo naa l’osu keta odun 1893 si osu kokanla odun 1894; Ipo naa s’ofo l’atigba naa titi di osu kerin odun 1896 ti Ajimoko kinni je, to si je titi di osu kesan-an odun 1901; Atayero lo odun mokandinlogun l’aaarin odun 1901 si 1920; Aromolaran akoko je l’odun 1920 si 1942.  

Aarin odun 1942 naa ni won tun yan iyawo Ajimoko gege bi adele oba, toun je titi di osu kesan-an odun naa. Ojo kewaa osu kesan-an odun 1942 ni iwon yan Fidipote Ajimoko keji to je titi ojo kejidinlogun osu kewaa odun 1956. Ojo naa ni won ti yan J. E. Awodiya gege bi adele oba, to si je adele wo odun 1957. Fiwajoye Ogunmokun to je Biiladu keta lo je l’odun 1957 si osu keje odun 1963.

Adele ni won tun yan l’osu keje odun 1963 naa titi odun 1966 ti won fi ri Oba Peter Adeniran Olatunji Agunlejika keji to je titi osu kesan odun 1981. Ipo naa s’ofo, won ko yan adele titi ti won fi s’awari Omoba Gabriel Adekunle Aromolaran keji l’odun 1982.

Bi e ba ka gbogbo awon oba to ti je saaju ko to o kan Oba Gabriel Adekunle, e maa ri i pe mokandinlogoji ni gbogbo, Oba Aromolaran keji ni oba ogoji to je Owa Obokun Adimilu t’ilu Ilesa/Ijesa. Kaaaaaabiyesi ooooooo!

Ibẹre pẹpẹ

Ojo ketala osu kewaa odun 1937 ni won bi Kabiyesi, Oba Dokita Gabriel Adekunle Aromolaran keji, Owa Obokun Adimula t’ilu Ijesa ati olori oba ilu Ijesa n’ipinle Osun. Aromolaran akoko, Oba Oduyomade ni baba re, n’igba ti iya re je Olori Tinuola Oduyomade Aromolaran. Oba Gabriel Adekunle ni abigbeyin mama re. Ile eko Otapete Methodist to wa n’ilu Ilesa lo ti bere eto eko re, to si lo o pari re n’ile eko Agbeni Methodist to wa ni Oke-Ado n’ilu Ibadan, ipinle Oyo. Oba Gabriel mo iwe daadaa, eyi lo je ko lo sise olukoni lati fi ri owo ran ara re tesiwaju. Idi ise olukoni yii lo wa to fi ri anfaani lati kekoo siwaju si i n’ile eko Wesley College, iyen ile eko awon olukoni to wa l’agbegbe Elekuro n’ilu Ibadan.

Bo se kuro nibe lo tun gba ilu Abeokuta lo lati lo kekoo nipa Physics, Chemistry, Biology ati Isiro ti a mo si Mathematics n’ile eko girama tílu Abeokuta, iyen Abeokuta Grammar School n’ipinle Ogun.

Fasiti t’awon koleeji ti won gbe wa lati ilu London, eyi ti won n pe ni fasiti Ibadan (University of Ibadan, UI) bayii ni Kabiyesi lo, nibi to ti kekoo gboye B.Sc ninu eko Economics. O tun kekoo nipa Public Administration ni fasiti Ife to wa n’ilu Ibadan n’igba naa ko to o lo tesiwaju nilu Pittsburgh/Pennsylvania, iyen l’Amerika lati lo o gboye Masters nipa Mathematical Economics.

Iwaju ni Oba Gabriel Adekunle maa n fe wa ni gbogbo igba, eyi lo je ko tun tiraka lati gba oye Omowe, iyen Ph.D, to si pada gba a ninu eko Development Economics.

Igba ti Kabiyesi ka iwe tan lo wa si Naijiria, nibi to ti darapo lati se ise ijoba nigba ijoba elekun-o-jekun, iyen Old Western Region, to si sise kaakiri eka. O sise de ipo igbakeji akowe agba ko to di pe o kowe f’ipo sile wi pe oun ko sise mo. Ko pe to kowe f’ise sile lo da ileese ara re ti won ti n te iwe jade, eyi to pe ni Aromolaran Publishing Company Limited sile nilu Ibadan, ipinle Oyo. Ojo kinni osu kokanla odun 1971 lo bere ni pereu. Kaakiri apa kan nile adulawo ti i se Africa (West Coast of Africa) bi i Ghana, Sierra Leone at’awon mi in lo ni eka ileese yii si, to si tun ni silu london ati New York l’Amerika (USA).

Bi wọn ṣe yan Kabiyesi

Idile merin lo n je Oba Owa Obokun Adimula nilu ilesa, awon idile naa ni idile Biladu, Bilagbayo, Bilaro ati Bilayirere. Okan lara awon idile yii ni Kabiyesi ti wa.
A ko le so pe Kabiyesi naa n riran bi i ti Jesefu inu bibeli to ti ri ojo iwaju re, tori pe lati kekere naa ni Kabiyesi ti mo pe oun yoo je oba l’ojo kan. Kabiyesi ti fi ipo yii la ala laimoye igba. Kabiyesi so ala re nipa wi pe oun ba ara oun lori aga oba, sugbon ti won ni oro omode lo n so, igba to si pe kabiyesi bere si i ni imo daadaa, lo di pe ko s’oro naa sita mo ki won ma ba a pa kadara da saida.

Adedaa si daabobo Kabiyesi kuro l’owo awon ota to see se ki won ti pa a lati kekere. Kabiyesi ko je ki ipo yii wo oun loju, tabi je e l’ogun, to si je pe bo se n gbe igbesi aye re lo naa lo tun n ronu nipa re. Igba to ya lo gbe e kuro l’okan, to si je pe bi ala lo ri n’igba ti won lo fi iroyin ayo naa to o leti wi pe oun ni ipo naa kan.
Ileri ati ipinnu ti Kabiyesi se n’igba to bere si i la ala n’ipa ipo oba ni pe boun yoo ba je oba ilu oun, ki iwe eri Omowe ti wa l’owo oun, eyi to tiraka lati ri i pe oun gba a ko to di pe ipo naa te e l’owo.

Gbogbo omo ati olugbe ilu Ijesa patapata jakejado agbaye la gbo pe won panupo lati yan Oba Gabriel Adekunle Aromolaran keji. Ogunjo osu keji odun 1982 ni won ti yan Kabiyesi, sugbon ti won gbe ade le e l’ori gege bi Owa Obokun Adimula ogoji l’ojo keedogun osu karun-un odun 1982.

Oloogbe Bola Ige to je gomina ipinle Oyo atijo lo gbe ade le Owa Obokun Adimula l’ori, pelu ayeye nla n’igba naa.

Saaju asiko l’awon omo ilu naa ti n gburo Kabiyesi kaakiri agbaye nipa awon akitiyan lati mu idagbasoke ba ile Naijiria kaakiri agbaye, eyi gan an lo tun ye awon amuye ti won ri, ti won fi wo o pe Kabiyesi yoo je olugbala bi won ba yan an gege bi Oba won, to si ri bee loooto. Awon idagbasoke to de ba ilu Ijesa latigba ti Oba Aromolaran keji ti de ori ipo yii ko se e f’enu so.

Awon to ba mo bi ilu Ijesa se ri ko to o to odun 1982 ni ki won pada lo lonii lati mo boya oju kan soso ni won wa tabi won ti sun siwaju.

Awọn ipa rẹ lawujọ

Odu ti ki i saimo f’oloko ni Oba Gabriel Adekunle Aromolaran keji, Owa Obokun Adimula t’ilu Ijesa. Gbajugbaja ni l’aaarin awon onkowe l’orile-ede Naijiria ati nile Adulawo, to fi mo awon apa kan n’ile alawo funfun. Iwe to le ni ogorun-un ni Kabiyesi ti ko, to si je pe pupo re l’awon akekoo si n ka titi di asiko yii ni Naijiria, Ghana, Sieera-Leone at’awon mi in.

Oba Aromolaran ni Oba akoko l’orile-ede Naijiria ti yoo koko kekoo gboye Omowe (Ph.D) ninu eko Economics. Iwe re akoko to ko, eyi to gbe jade l’odun 1966, iyen Economics for West Africa ko s’eyin awon ore bi i Alabi Ogun ati Areoye Oyebola ti won jo ba a f’owo si.

Bi won se n ka awon iwe Kabiyesi n’ile eko alakobere, bee ni won n ka a  n’ile eko girama ati awon ile eko giga bi i fasiti, poli ati koleeji n’ile l’oko. Okan l’ara awon alakoso eto idanwo, iyen Examiner for General Certificate Education (GCE) Advanced Level Economics for West Africa Examination Council (WAEC) l’awon orile-ede bi i Naijiria, Sierra-Leone ati Ghana ni Kabiyesi je.

Kabiyesi giwa agba fasiti imo ero, iyen Federal University of Technology to wa nilu Yola, ipinle Adamawa l’aaarin odun 2002 si 2014, iyen fasiti ti won ti yi oruko re pada si Modibo Adama Federal University of Technology. E ma je ko ya yin lenu pe Kabiyesi tun kekoo gb’oye LLD Degree (Honoris Causa) ni fasiti kan naa yii.

Kabiyesi ni Aare igbimo awon oba alaye nilu Ijesa, iyen Ijesa Traditional Council, eyi to je pe ijoba ibile mejila ni won wa labe re, oun si ni alase l’ori gbogbo ipo, oye kaakiri gbogbo ilu Ijesa. Awon oba alade to to ogorun kan ni won wa labe akoso Alayeluwa, Oba Gabriel Adekunle Aromolaran keji.

Iwe ti ko din ni merinla ni kabiyesi tun ti ko l’aaarin igba to fi wa l’ori ipo naa titi di asiko yii. Awon ipa rere ti Kabiyesi ti ko ninu idagbasoke orile-ede yii lo je ki ijoba Naijiria fi oye CFR, iyen Commander of the Federal Republic of Nigeria ta a l’ore. Iwe ti ko din ni ogorun-un ni Kabiyesi ti gbe jade l’oruko ileese re yii.

Diẹ lara awọn iwe ti Kabiyesi ti gbe jade

West African economics; Economics of West Africa; Economic theory for West African students; As it was in the beginning; 85 model questions and answers on West African economics today; Modern economic analysis for West African students; Model questions and answers on West African government today for G.C.E. ("O". & "A".); W.A.S.C. & H.S.C. students; 70 questions and answers on economics of West Africa, for G.C.E., H.S.C., and university students.

Revision notes on government; Model questions & answers on 'O' level government; Modern textbook of government for West African students; Combined questions & answers on modern textbook of government; for West African School Certificate, General Certificate of Education ('O' & 'A'), and Higher School Certificate students; Combined questions & answers on British & West African economic history; Questions & answers on 'O' level economics of West Africa; Modern economic analysis : (for "O" Level students); Combined model questions & answers on economics of West Africa and modern economic analysis; Revision notes on 'O' level economics; Modern textbook on government (for 'O' level students) at’awon mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI