Ọọni Ifẹ ati ileeṣẹ Adron Homes tọwọ bọwe adehun lori agbatẹru Ọdún Ọlọ́jọ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 23, 2024

Ọọni Ifẹ ati ileeṣẹ Adron Homes tọwọ bọwe adehun lori agbatẹru Ọdún Ọlọ́jọ́


Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi ti buwọ lu iwe adehun to fontẹ lu ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited lati jẹ ọkan gboogi lara awọn ti yoo ṣagbatẹru ayẹyẹ Ọdun Ọlọjọ ti ọdun 2024.
 
Eyii lo waye lati gbe aṣa, iṣe ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba larugẹ niluu Ile-Ifẹ, ipinlẹ Ọṣun.
 
Ninu ajọṣepọ ileeṣẹ Adron Homes pẹlu Ile Oduduwa fun ti ayẹyẹ Ọdun Ọlọjọ yii, a gbọ pe gbogbo eto lo ti wa ninu ilana alakalẹ fun agbatẹru ọhun.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, nibi abẹwo ti awọn alakoso ileeṣẹ Adron Homes ṣe lọ si Aafin Ọọni Ifẹ, eyi ti alakoso agba, Arabinrin Adenikẹ Ajọbọ lewaju fun, Ọba Adeyẹye sọ pe oun fontẹ lu ileeṣẹ naa lati jẹ ọkan gboogi lara awọn alatilẹyin fun ayẹyẹ ọdun yii.
 
Lati bi ọdun mẹfa sẹyin ni ileeṣẹ Adron Homes ti n jẹ okan pataki lara awọn to n ṣagbatẹru ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ, eyi ti wọn fi n saami ọdun tuntun nilẹ Yoruba.
 
Kaakiri agbaye ni awọn eeyan ti n wa siluu Ilu Ifẹ fun ti ayẹyẹ ọdun ọlọjọ.














No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI