Ọkan lara awọn oludije sipo alaga ijọba ibilẹ niluu Ọffa, ipinlẹ Kwara ti kọwe sọ pe oun ko le darapọ mọ eto itakurọsọ to waye lonii, ọjọ Ẹti.
Ọnarebu Surajudeen Ọlaitan Balogun to n dije du ipo alaga ijọba ibilẹ Ọffa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord jẹ ko di mimọ pe igba akọkọ ree ti iru itakurọsọ bẹẹ yoo waye.
Bakan naa lo sọ pe asiko ti wọn fi eto itakurọsọ naa to oun leti kere si igba ti wọn gbe e kalẹ, fun idi eyi, o loun ko le darapọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ileeṣẹ kan ti wọn pe ni ONEIH- Kola Balogun Technology Centre lo ṣagbekalẹ eto itakurọsọ ọhun, leyi ti yoo fun awọn oludije lanfaani lati sọ erongba ati ipinnu wọn fun ipo ti wọn n du.
Oni, ọjọ Ẹti, Furaide ni eto naa waye niluu Ọffa, lojuna lati mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ilu ọhun.
Wọnyi ni lẹta ti Ọnarebu Balogun kọ:
No comments:
Post a Comment