Bi ayẹyẹ igbade ọdun kan ṣe bẹrẹ niluu Ilawọ, eyi ti Olu Orile-Ilawọ Ọba Alexadar Oluṣẹgun MacGregor gba ade, bẹẹ ni Kabiyesi ti bẹrẹ sii ṣiṣọ loju ọpọ awọn iṣẹ akanṣe onidagbasoke laarin ilu.
Lara wọn ni ti ile iwosan alabọde ti Kabiyesi ṣi lọjọ Aje, ọsẹ ti a wa yii.
Apẹẹrẹ nla leyi jẹ ninu itan idagbasoke ilu Orile-Ilawọ lapapọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ki Ọba MacGregor to dori aleefa lo ti n ṣe oriṣiriṣi akanṣe iṣẹ idagbasoke siluu, bo ṣe n ro ọdọ lagbara, lo n ṣe iranwọ fawọn akẹkọọ, ọmọde, opo ati awọn arugbo.
Akẹkọọ to le ni ẹẹdẹgbẹta ni wọn wa labẹ eto ẹkọ ọfẹ ti Ọba MacGregor gbe kalẹ lati bi ọdun mẹfa le diẹ sẹyin.
Eto ayẹyẹ igbade ọdun kan yii lo bẹrẹ ni pẹrẹu lọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan, ọdun 2024 pẹlu idije ere bọọlu alafẹsẹgba laarin awọn abule ati ilu to wa labẹ Orile Ilawọ.
Papa iṣere ile-ẹkọ girama tiluu Abẹokuta ni idije ọhun ti waye lati ṣagbelarugẹ fun ifẹ, iṣọkan ati alaafia ilu Ilawọ.
Ọjọ keji to wa lara eto ayẹyẹ ọdun kan naa ni ti ṣiṣi ile iwosan alabọde yii, ti awọ bii alaga ijọba ibilẹ Ọdẹda, Ọnarebu Fọlaṣade Adeyẹmọ ati awọn alẹnulọrọ laarin ilu wa nibẹ.
Awọn akọṣẹmọṣẹ oniṣegun oyinbo ko gbẹyin nibi ifilọlẹ ile iwosan alabọde ọhun, nibi ti gbogbo wọn ti gboriyin fun kabiyesi, Ọba Oluṣẹgun MacGregor lori akanṣe iṣẹ naa.
Nigba to n sọrọ, Ọnarebu Adeyẹmọ sọ pe oriire nla lo de ba ilu Ilawọ pẹlu ile iwosan alabọde to wọluu yii, nitori pe awọn araalu yoo bẹrẹ sii jẹ anfaani eto ilera.
Adeyẹmọ tẹsiwaju pe Ọba MacGregor n wa ilọsiwaju fun ilu Ilawọ, fun idi eyi, gbogbo ilu ni lati fi atilẹyin wọn han si kabiyesi.
No comments:
Post a Comment