Ó mà ṣe o! Èéfín jẹnẹrétọ̀ pa Ikechukwu mọ́lé l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 23, 2024

Ó mà ṣe o! Èéfín jẹnẹrétọ̀ pa Ikechukwu mọ́lé l'Ogun


Kayeefi nla gba a lọrọ iku ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Nwachukwu Ikechukwu ṣi n jẹ fun ọpọ awọn eeyan, paapaa awọn ara agbegbe Owode-Ẹgba nipinlẹ Ogun.
 
Eefin jẹnẹretọ ni iroyin fi to wa leti pe o ṣeku pa Ikechukwu adugbo kan ti wọn pe ni Shogoye niluu owode-Ẹgba.
 
AWIKONKO rii gbọ pe inu yara igbalejo (parlour) ni Ikechukwu ati iyawo rẹ, oyin falọdun gbe jẹnẹretọ ọhun si ni nnkan bi agogo ni nnkan bi agogo mẹwaa alẹ Ọjọbọ, ọsẹ to kọja yii.

Ọkan lara awọn ara adugbo to n da ajọ si Oyin lọwọ, Ọladayọ Ọlaṣubomi ni wọn lo kofiri awọn tọkọ taya naa nibi ti wọn ti n pokaka iku.

Olaṣubomi lo pariwo sita bo ṣe ri ohun to ṣẹlẹ, to si mu ki awọn ara dugbo sare wọle lati wo ohun to n ṣẹlẹ, koda, alaga adugbo naa sare debẹ.
 
Alaga adugbo naa, Showunmi Sunday, lo gba teṣan ọlọpaa, ẹkun Owode-Ẹgba lọ lati fọrọ ọhun to wọn leti.
 
Agbẹnusọ ọlọpaa, Ọmọlọla Odutọla lasiko to n gbe iroyin naa sawọn akọroyin leti, o loju ẹsẹ tawọn ọlọpaa ti gbọ, ni wọn ti debẹ lati foju ri ohun to ṣẹlẹ.
 
Odutọla jẹ ko di mimọ pe wọn ti gbe obinrin naa lọ si ọsibitu fun itọju, bo tilẹ jẹ pe ile ni ọkọ rẹ ku si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI