NNPCL lóun ṣetán láti ta epo fún Dangote pẹ̀lú owó náírà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 3, 2024

NNPCL lóun ṣetán láti ta epo fún Dangote pẹ̀lú owó náírà


Ileeṣẹ to n ṣobojuto epo rọbii lorileede Naijiria, Nigerian National Petroleum Company Limited, NNPCL, ati ileeṣẹ Dangote Petroleum Refinery lawọn ti fẹnuko lori tita epo rọbii ni owo naira.


Ajọ Nigerian Midstream and Downstream Petroleum Regulatory Authority, NMDPRA, lo fi iroyin yii lede loju opo ayelujara 'X' wọn lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee

Gẹgẹ bi NMDPRA ṣe sọ, wọn ni NNPCL ti pari ọrọ ati ajọsọ lati bẹrẹ sii ta epo rọbii fun ileeṣẹ ifọpo Dangote Refinery ni owo naira ti wọn n na ni Naijiria.

Ajọ naa tun fi kun ọrọ rẹ pe erongba ati ipinnu ileeṣẹ ifọpo yii ni lati maa gbe miliọnu marundinlọgbọn epo bẹntiroolu jade fun tita lojumọ, iyẹn ninu oṣu Kẹsan, ọdun 2024.

Bakan naa ni wọn tun jẹ ko di mimọ pe nigba ti yoo ba fi di oṣu Kẹwaa, wọn yoo sọ ọ di miliọnu lọna ọgbọn lita ti wọn yoo maa gbe jade lojumọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI