Nitori atunṣe, ijọba Kwara ti opopona Post Office pa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 27, 2024

Nitori atunṣe, ijọba Kwara ti opopona Post Office pa


Ijọba ipinlẹ Kwara ti gunle atunṣe opopona Post Office si Emir lojuna lati mu ki igbokegbodo ọkọ lọ ni irọrun fun igbadun araalu.

Fun idi eyi, ijọba ti rawọ ẹbẹ si awọn araalu lati bẹrẹ sii lo awọn opopona miran pati de ibi ti wọn n lọ titi digba ti atunṣe ọhun yoo fi pari

Atunṣe naa ni ijọba sọ pe yoo mu idagbasoke ba eto ọrọ aje, nipa igbokegbodo ọkọ to ja geere lai ni idiwọ.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ to n ri sọrọ iṣẹ ati igbokegbodo ọkọ nipinlẹ naa gbe jade, wọn rọ awọn awakọ lati gba awọn ọna miran to wa nitosi.

Awọn to n bọ lati agbegbe Maraba, ki wọn maa gba ori afara Post Office, nigba ti awọn to n bọ lati agbegbe garaaji Ọffa, ki wọn gba opopona Zulu Gambari.







No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI