Kí ni ojúṣe 'SPY' àti ìyàtọ̀ wọn sí ojúlówó iṣẹ́ ọlọ́pàá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 12, 2024

Kí ni ojúṣe 'SPY' àti ìyàtọ̀ wọn sí ojúlówó iṣẹ́ ọlọ́pàá


Ileeṣẹ ọlọpaa lorileede Naijiria ti kede sita wi pe iyatọ wa laarin wọn pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn pe ni
Supernumerary Police Officer (SPO).
 
Ọmọọba Olumiyiwa Adejọbi to jẹ agbẹnusọ agba fun ileeṣẹ ọlọpaa lo kede eyi loju opo ayelujara ti 'X' rẹ laipẹ yii, nigba to n tako fọnran agbofinro kan to n sọrọ nipa eto idibo to fẹẹ waye nipinlẹ Ẹdo.
 
Adejọbi sọ pe iṣẹ ti awọn ọlọpaa Supernumerary Police Officer (SPO) yii n ṣe yatọ si ti ojulowo ọlọpaa, bo tilẹ jẹ awọon ni wọn ṣe idanilẹkọọ fun wọn.

Bakan naa lo sọ pe aṣọ ti wọn n wọ yatọ si eyi ti ojulowo ọlọpaa n wọ, bo tilẹ jẹ pe o fara jọ ara wọn, ṣugbọn sibẹ, o ni araalu ni lati mọ iyatọ.
 
Adejọbi ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe ọkunrin, oṣiṣẹ SPY naa ko ṣiṣẹ fun wọn, bẹẹ si ni ko gba ẹnu ọlọpaa sọrọ.
 
O jẹ ko di mimọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin naa, awọn si ti n fọrọ wa a lẹnu wo lori awọn ọrọ to sọ, eyi to n ja rainrain lori ayelujara.
 

Ojuṣe SPY

Ṣiṣe akoso ero ati aabo ibi eto ayẹyẹ: Awọn ọlọpaa tuntun yii ni yoo maa ṣabojuto awọn ero ti wọn ba wa nibi ayẹyẹ tabi eto pataki lawujo, to fi mọ ifẹhonuhan ati apẹjọ elero rẹpẹtẹ.

Didari ọkọ lopopona: Awọn ọlọpaa yii ni yoo maa ṣabojuto lilọ geere igbokegbodo ọkọ nigba ti eto tabi ayẹyẹ ba waye lawọn agbegbe kaakiri Naijiria.

Iranwọ lasiko iṣẹlẹ pajawiri: Nigbakugba ti ijamba tabi iṣẹlẹ ijamba pajawiri ba waye, awọn ọlọpaa wọnyi yoo maa ṣe iranwọ lati daabo bo ẹmi ati dukia, ni iranwọ fun awọn ọlọpaa ti awọn araalu mọ.

Aabo ilu: Awọn ọlọpaa yii yoo maa lọ kaakiri awọn agbegbe ati igberiko lati rii pe awọn eeyan n tẹle ofin, wọn si n ri daju pe ko si iwa ọdaran kankan lagbegbe ti wọn ba wa.

Ijiroro pẹlu awọn adugbo: Wọn yoo maa ṣiṣẹ lawọn adugbo, bẹẹ si ni wọn yoo ni ajọṣepọ to dan mọnran pẹlu awọn alakoso adugbo ati agbegbe fun alaafia ati aabo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI