Jonathan tu aṣiri idi to fi yọ Sanusi nipo gẹgẹ bi gomina CBN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 27, 2024

Jonathan tu aṣiri idi to fi yọ Sanusi nipo gẹgẹ bi gomina CBN


Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Goodluck Ebele Jonathan, l'Ọjọbọ, ọsẹ yii ti sọ awọn aṣiri to ṣokunkun sawọn ọmọ Naijiria lori idi pataki ti ijọba rẹ fi yọ Ọmọwe Sanusi Lamido Sanusi nipo gẹgẹ bii gomina ile ifowopamọ agba ilẹ naa, CBN
 
Jonathan sọ pe owo kan to din diẹ ni aadọta biliọnu owo dọla ($49.8bn) ni Lamido Sanusi, to ti wa pada di Emir Muhammad Sanusi bayii fẹsun rẹ kan wi pe o sọnu lapo ijọba Naijiria.
 
Bakan naa ni Jonathan jẹ ko di mimọ pe oun ko mọ nnkankan bipa bi wọn ṣe rọ ọ nipo gomina CBN lọdun naa lọhun.
 
Siwaju sii lo sọ pe ko si owo kankan to sọnu lasiko iṣejọba oun, bi ko ṣe pe banki apapọ ilẹ Naijiria labẹ iṣakoso Sanusi mọ-ọn-mọ gbe esun naa dide lasiko naa lasan ni.
 
Ilu Abuja ni Aarẹ Jonathan ti sọrọ yii nibi eto ifilọlẹ iwe kan ti wọn pe akori rẹ ni “Public Policy and Agents Interests: Perspectives from the Emerging World,” ti minisita feto iṣuna nigba kan ri, Ọmọwe Shamsudeen Usman jẹ ọkan lara awọn to kọ ọ.
 
Nigba to n tako awọn ọrọ gomina CBN tẹlẹri, nibi to ti sọ pe wọn le oun danu nipo nitori aṣiri toun tu sita nipa owo to poora lasiko iṣejọba Aarẹ Jonathan.
 
Ninu iwe naa ni Sanusi ti ṣalaye pe ko si idi meji ti wọn fi yọ  oun nipo gẹgẹ bii gomina, bi ko ṣe ti aṣiri owo toun tu sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI