Ìjọba Kwara rọ àwọn ìjọba ìbílẹ̀ láti yọnda katakata fáwọn àgbẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 3, 2024

Ìjọba Kwara rọ àwọn ìjọba ìbílẹ̀ láti yọnda katakata fáwọn àgbẹ̀


Ijọba ipinlẹ Kwara ti rọ gbogbo awọn alakoso eto iṣejọba l'awọn ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to so ipinlẹ ọhun papọ lati yọnda katakata fun awọn agbẹ, paapaa awọn agbẹ alabọọde.

Kọmiṣanna feto ijọba ibilẹ, oye jijẹ ati idagbasoke awọn agbegbe, Ọnarebu Abubakar Bata lo rọ awọn alakoso ijọba ibilẹ ọhun laipẹ yii.

Ọnarebu Bata ni bi awọn alakoso eto iṣejọba ibilẹ ba yọnda awọn katakata tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ra fawọn agbẹ, yoo mu imugbooro ba pipese ounjẹ fun ilu.

Laipẹ yii ni awọn ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara ṣiṣọ loju awọn katakata ti wọn ṣẹṣẹ ra lati mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba eto iṣẹ agbẹ nipinlẹ naa.

Awọn katakata wọnyi ni wọn ra loriṣiriṣi bii eyi ti wọn fi n roko, eyi ti wọn fi n gbin ohun ọgbin, eyi ti wọn fi n ko ire oko ati bẹẹbẹẹlọ.

Bata ni inu oun dun pupọ lati rii pe awọn ijọba ibilẹ ti n lo awọn owo wọn daadaa lọna to tọ, ati pe awọn katakata naa yoo mu imugbooro ba eto iṣẹ agbẹ l'awọn igberiko.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI