Ijọba Kwara bẹrẹ atunṣe afara Moro fun irọrun araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 19, 2024

Ijọba Kwara bẹrẹ atunṣe afara Moro fun irọrun araalu


Lojuna lati mu ki igbokegbodo ọkọ lọ ni irọrun fawọn araalu, Gomina AbdulRahman Abdulrazaq ti paṣẹ pe ki atunṣe bẹrẹ lori afara onirin Moro titi digba ti ijọba apapọ Naijiria yoo fi wa nnkan ṣe sii.

Lati bi oṣu meloo sẹyin ni afara ọhun ti dẹnukọlẹ, ti ko si ṣee gba rara fawọn araalu.

Bi awọn awakọ ko ṣe le gba afara naa ni awọn to n fi ẹsẹ rin ko le gbagbẹ kọja.

Ipo ti afara ọhun wa ti mu ifasẹyin ba eto ọrọ aje agbegbe naa, paapaa igbokegbodo ọkọ lati bi oṣu diẹ sẹyin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI