Igbákejì Ààrẹ Nàìjíríà, Shettima àti Gómìnà AbdulRazaq ṣàbẹ̀wò sáwọn ará Niger tí àgbàrá òjò ṣe lọ́ṣẹ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, September 15, 2024

Igbákejì Ààrẹ Nàìjíríà, Shettima àti Gómìnà AbdulRazaq ṣàbẹ̀wò sáwọn ará Niger tí àgbàrá òjò ṣe lọ́ṣẹ́


Igbakeji Aarẹ orileede Naijiria, Kashim Shettima ati Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti ṣabẹwo si awọn araalu Niger, nibi ti agbra ojo ti ṣọṣẹ.

Ko ju bii wakati mẹrinlelogun ti gomina ipinlẹ Kwara naa, AbdulRazaq lewaju ẹgbẹ gomina Naijiria lọ siluu naa lati ba Gomina Babagana Umara Zulum kẹdun ni igbakeji aarẹ tun lọ yọju si wọn.

Agbara ojo to ṣọṣẹ buruku naa lo sọ ẹgbẹẹgbẹrun eeyan di alainile lori, to si tun gbe awọn eeyan lọ.

Bo ṣe ba ile jẹ, naa lo ba ile iwosan, ile ẹkọ ati okoowo jẹ loriṣiriṣi.

Ọjọ Ẹti to kọja yii ni igbakeji aarẹ ati gomina ipinlẹ Kwara tẹkọ leti lọ sibẹ lati ba ijọba ipinlẹ naa ati awọn araalu kẹdun.

“Ni ana (Furaide), mo darapọ mọ ìkọ ijọba apapọ ti igbakeji aarẹ, Kashim Shettima lewaju fun lati lọ ṣe abẹwo si awọn ti agbara ojo gba ile ati dukia lori wọn, ti wọn wa ni Gwada, Shiroro, ipinlẹ Niger.

“Igbakeji jiṣẹ iranwọ ti aarẹ ran an, nipa fifi atilẹyin han, paapaa si awọn ti agbara ojo ṣe lọṣẹ ni awọn apa kan nipinlẹ ọhun,” Gomina Abdulrazaq jẹ ko di mimọ.

Lara awọn to tun wa ninu ikọ ọhun ni: minisita feto iroyin ati ilanilọyẹ, Mohammed Idris; minisita feto ipinlẹ, iṣẹ agbẹ ati aabo ounjẹ, Abdullahi Sabi; igbakeji olori oṣiṣẹ aarẹ, Ibrahim Hadejia; ati alakoso agba fun ajọ NEMA, Zubaida Umar.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI