Ìdíje eré ìdárayá ilé-iṣẹ́ Adron Homes gbọ̀nà àrà yọ pẹ̀lú Daniel Amokachi àti Mutiu Adepọju - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 19, 2024

Ìdíje eré ìdárayá ilé-iṣẹ́ Adron Homes gbọ̀nà àrà yọ pẹ̀lú Daniel Amokachi àti Mutiu Adepọju


Ọna ara-ọtọ ni idije ere idaraya ti ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited ti ọdun 2024 gba yọ, pẹlu awọn alakalẹ eto ọlọkan-o-jọkan.

Idije ere idaraya ti ọdun 2024 ọhun ti wọn pe akori rẹ ni ‘Fit to Be the Biggest’ ni yoo jẹ ẹlẹẹkeje iru rẹ.

Ko sohun meji ti yoo mu ki eto ere idaraya ti ọdun yii da yatọ si awọn ọdun yooku, bi ko ṣe ti bi awọn akọṣẹmọṣẹ elere idaraya, ti wọn tun ti figba kan ri jẹ gbajugbaja agbabọọlu ṣe fẹẹ kopa to jọju nibẹ.

Ogbontarigi agbabọọlu ikọ Super Eagles nni, Daniel Amokachi ati Mutiu Adepọju wa lara awọn ti yoo mu ki idije ọhun lọ bo ṣe yẹ.

Papa iṣere Lekan Salami to wa lagbegbe Adamasingba niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ni akanṣe ere idaraya naa yoo ti waye laarin ọjọ kọkandinlọgbọn si ọgbọn ọjọ, oṣu kọkanla, ọdun 2024.

Eyii si ni yoo jẹ igba keji ti ilu Ibadan yoo maa gbalejo fun idije yii.

Idije ere idaraya ti ileeṣẹ Adron Homes yii ni wọn ṣagbekalẹ rẹ lati ṣe agbelarugẹ fun wiwa ni ilera pipe, ati ibaṣepọ to dan mọnran laarin awọn agbegbe nipa ere idaraya.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI