Idibo: Oriire nla lo wọle tọ APC ni Kwara - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 23, 2024

Idibo: Oriire nla lo wọle tọ APC ni Kwara - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba gbogbo awọn oludije to jawe olubori sipo alaga kansu nipinlẹ naa yọ, to si tun ki wọn ku oriire.

Lopin ọsẹ to kọja yii ni eto idibo sipo alaga kansu kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara waye, ti awọn oludije lẹgbẹ APC si jawe olubori patapata.

Alaga kansu mẹrindinlogun ati kansẹlọ ọtalelaadọwaa (193) ni wọn jawe olubori ninu eto idibo naa ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

Gomina AbdulRazaq wa ki awọn adari ẹgbẹ APC lori aṣeyọri wọn nipa akitiyan ti wọn ṣe ṣaaju ọjọ idibo.

Bakan naa lo gbe oṣuba kare fun ajọ eleto idibo KWSIEC lori agbekalẹ wọn, eyi to mu ki eto idibo ọhun lọ bo ti yẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI