Ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀: Mo bẹ Gómìnà Dàpọ̀ Abíọ́dún láti jẹ́ kí aráàlú dìbò yan ẹni tó wù wọ́n - Kọ́múréèdì Abíọ́dún - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, September 3, 2024

Ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀: Mo bẹ Gómìnà Dàpọ̀ Abíọ́dún láti jẹ́ kí aráàlú dìbò yan ẹni tó wù wọ́n - Kọ́múréèdì Abíọ́dún


Ọkan lara awọn oludije s’ipo Kanṣelọ nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Ismail Taalabi Abiọdun, ti gba ijọba ipinlẹ naa labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun lamọran lati ma ṣe lo agbara lori eto idibo ijọba ibilẹ to n bọ lọna.

Kọmureedi Abiọdun to n jade du ipo naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Congress, ADC ni wọọdu keji, ijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta lo rọ ijọba laipẹ yii lasiko to n b’AWIKONKO sọrọ.

Ọkunrin ọmọ bibi ilu Ilugun ti Abẹokuta naa sọ pe kii ṣe iroyin tuntun wi pe ijọba to ba wa lori iṣakoso lo maa n lo ọwọ agbara lori eto idibo ijọba ibilẹ, ati pe niṣe ni wọn maa n kọ orukọ awọn ti wọn ba fẹ fun ajọ ẹlẹto idibo ijọba ibilẹ nipinlẹ naa, OGSIEC lati kede sita.

Ṣugbọn Kọmureedi Abiọdun sọ pe idibo ijọba ibilẹ tọdun yii ko gbọdọ ri bẹẹ.

Abiọdun sọ pe ki ijọba fi awọn oludije silẹ lati lọ sori papa fun ifigagbaga, ki wọn si jẹ ki araalu yan ẹni ti wọn ba fẹ sipo, nitori pe eyi gan-an ni yoo jẹ ki eto oṣelu awarawa fẹsẹ mulẹ.

O ni “Mo rọ ajọ eleto idibo abẹle nipinlẹ Ogun, OGSIEC lati gba awọn araalu laaye lati yan ẹni to ba wu wọn sipo, ki wọn ma ṣe lo agbara lori ẹnikẹni, nitori pe asiko ni gbogbo nnkan. O ṣee ṣe ki ilu ti wọn fi agbara yan awọn eeyan sipo ma ni itẹsiwaju.

“Ẹ jẹ ka fi otitọ ṣe ohun gbogbo ti a ba n ṣe. Bakan naa, mo tun n fi asiko yii bẹ Ọmọba Dapọ Abiọdun lati faaye silẹ fun eto idibo alalaafia, ki wọn gba awọn oludibo laaye lati lọ sori papa fun ifigagbaga lai ṣe ojusaaju ẹnikẹni.

“Ki wọn jẹ ki awọn araalu yan ẹni to wu wọn lọkan, ki wọn ma si ṣe yan le awọn araalu lori. Mo bẹ Ọmọba Dapọ Abiọdun lati fun gbogbo eeyan lanfaani lati ṣe ẹtọ rẹ labẹ ofin.”


Nigba to n sọrọ nipa afojusun rẹ, ati idi pataki to fi fẹẹ jade du ipo Kansẹlọ yii, Kọmureedi Abiọdun jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn to ti n ṣoju agbegbe yii nidi oṣelu ni ko tii sẹni to ṣe ohun ti awọn eeyan n fẹ, bi ko ṣe pe imọ tara wọn nikan ni wọn n ba lọ.

O loun sunmọ ilu daadaa, nitori pe ibẹ loun n gbe, toun si mọ awọn ohun to n jẹ wọn niya pupọ nibẹ, idi pataki to fi lawọn eeyan gba oun lamọran lati jade lọ ṣoju wọn.

“Ọmọ bibi ilu Ilugun ni Adedọtun to wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ti a wa yii ni mo jẹ. Wọọdu keji yii naa si ni mo ti wa. Ibẹ ni wọn bi mi si, ti mo si lọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ, girama ati ile-ẹkọ giga.

“Agbegbe yii ni mo n gbe, mo si sunmọ awọn eeyan mi lati mọ ohun ti wọn n fẹ. Ọpọ awọn to ti n jade lati ṣoju wa ni wọn ko tii ṣe nnkan ohun ti awọn eeyan n fẹ. Awọn to n jade yii ko mọ adojukọ wa lagbegbe yii nitori pe wọn ko duro sile.

“Ọpọ nnkan to n jẹ wa niya lo jẹ ki n ronu lati jade du ipo yii, paapaa lori ọgbọn, imọ ati oye ti mo ni lati fi mu idagbasoke wọnu ilu. Gẹgẹ bi ọdọ mo ni igbagbọ pe bi awọn araalu ba dibo fun mi, ti mo si de ipo yii, maa lo imọ iriri mi lawujọ lati fi mu idagbasoke ati itẹsiwaju ba agbegbe ti mo fẹ lọ ṣoju yii.

“Owo ati idajọ ile-ẹjọ lori owo ijọba ibilẹ kọ lo mu ki n pinnu lati jade du ipo yii, nitori pe erongba naa ti wa lọkan mi tipẹ, mo si ri asiko yii gẹgẹ bi asiko to dara. Kani to ba jẹ ti owo ni, ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba lọwọ ni mi o ba jade labẹ rẹ, ṣugbọn rara, nko ṣe bẹẹ.

“Ọpọ awọn eeyan lo mọ mi ladugbo ti mo fẹẹ lọ ṣoju yii ni wọn mọ mi si ajafẹtọ ọmọniyan, wọn si nigbagbọ ninu mi pe maa ṣe daadaa bi mo ba depo. Awọn ara agbegbe mi gan-an lo tubọ gba mi lamọran wi pe ki n jade fun ipo Kanṣelọ.

“Olodumare ni ọba alagbara, ọpọ eeyan lo ti gba mi lamọran lati ma ṣe jade, wi pe wọn maa kọ ibo naa ni, kii ṣe idibo ni wọn fẹẹ lo. Ṣugbọn mo nigbagbọ pe to ba jẹ Olodumare lo fẹ mi nipo yii, ko sẹni to le yii pada,” o kadi ọrọ rẹ.


Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe oṣelu toun wa ṣe kii ṣe oṣelu boo ba o pa, boo ba a o bu lẹsẹ, bi ko ṣe lati tubọ gbe ifẹ ati iṣọkan agbegbe, paapaa ipinlẹ Ogun ati orileede Naijiria lapapọ larugẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI