Gómìnà AbdulRazaq buwọ́lu ìdánwò ìgbéga fún àwọn olùkọ́ TESCOM ti ọdún 2023 si 2024 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 12, 2024

Gómìnà AbdulRazaq buwọ́lu ìdánwò ìgbéga fún àwọn olùkọ́ TESCOM ti ọdún 2023 si 2024


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti buwọlu idanwo igbega fun awọn olukọ ti wọn wa labẹ aburada TESCOM iyẹn Kwara State Teaching Service Commission ti ọdun 2023 si 2024.

Alaga ajọ TESCOM, Mallam Bello Tauheed Abubakar lo sọ eyi di mimọ niluu Ilọrin lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii lasiko to n ba awọn oṣiṣẹ rẹ sọrọ.

Mallam Abubakar sọ pe Gomina AbdulRazaq buwọlu idanwo igbega ọhun ni ibamu pẹlu awọn ileri rẹ si gbigbaruku ti igbayegbadun awọn oṣiṣẹ, paapaa awọn olukọ.

Bello jẹ ko di mimọ pe gbara ti gomina ti de ipo iṣakoso lọdun 2019, lo ti bẹrẹ sii buwọlu awọn igbega to ti yẹ lati ọdun 2015, 2016, 2017, to si tun n ṣe bẹẹ titi di asiko yii.

Alaga naa wa rọ awọn oṣiṣẹ TESCOM lati farajin fun iṣẹ wọn, ki itẹsiwaju le tubọ maa de ba eto ẹkọ pẹlu ileri wi pe ijọba Kwara yoo tubọ maa ṣe agbelarugẹ fun igbe aye irọrun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI