Gomina AbdulRazaq ti paṣẹ pe ki wọ bẹrẹ sii pin awọn ajilẹ ti ijọba apapọ sawọn ipinlẹ, paapaa ipinlẹ Kwara fun awọn agbẹ ko lai dawọ duro.
Amugbalẹgbẹ agba pataki fun gomina lori eto idagbasoke agbegbe, Ọmọwe Lawal Ọlọhungbẹbẹ lo sọ eyi di mimọ laipẹ yii.
Ọlọhungbẹbẹ sọ pe gbogbo awọn agbẹ ti wọn wa ni igberiko patapata ni yoo jẹ anfaani awọn ajilẹ ọhun, lati ro iṣẹ agbẹ ati ọgbin lagbara.
Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe awọn akopa ninu agbekalẹ akanṣe eto ti wọn ṣẹṣẹ pari, iyẹn Community-Based Organisations (CBOs) ni yoo jẹ anfaani ọhun, nitori pe wọn ti la idanilẹkọọ kọja.
Nigba to n gbe oṣuba kare fun gomina, Ọlọhungbẹbẹ jẹ ko di mimọ pe Gomina AbdulRazaq lo buwọ lu agbekalẹ eto idanilẹkọọ naa.
Bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe awọn ajilẹ naa yoo ṣe iranwọ pupọ fun agbelarugẹ iṣẹ agbẹ ati ọpọ ounjẹ lawujọ.
No comments:
Post a Comment