Gbajúgbajá akọ̀ròyìn, Wálé Abideen di agbẹnusọ àjọ TPI l'Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 12, 2024

Gbajúgbajá akọ̀ròyìn, Wálé Abideen di agbẹnusọ àjọ TPI l'Abuja


Ajọ kan ti wọn ya sọtọ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), eyi ti wọn pe ni The Progressive Institute ti kede Wale Abdulfatai Abideen to jẹ gbajugbaja akọroyin lorileede Naijiria gẹgẹ bi agbẹnusọ wọn.

Wale Abideen ni alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ iroyin Security Monitor to si tun ti di oriṣiriṣi ipo mu ninu ẹgbẹ akọroyin ati ajọ miran lorileede Naijiria.

Abideen gẹgẹ bi a ṣe gbọ ni yoo maa ṣakoso ẹka eto iroyin fun ajọ naa, ti wọn gbekale lati maa fi mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ẹgbẹ oṣelu APC, eyi ti wọn pe ni 'Policy Think Tank'.

Ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọja ni wọn da ajọ ọhun silẹ niluu Abuja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI