Ẹgbẹ YDC gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRazaq lori idajọ ododo to waye lori idigunjale banki Ọffa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 30, 2024

Ẹgbẹ YDC gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRazaq lori idajọ ododo to waye lori idigunjale banki Ọffa


Ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Youth for Democracy and Change (YDC) nipinlẹ Kwara ti gbe oṣuba kare fun Gomina Abdulrahman Abdulrazaq lori idajọ ododo to waye fun awọn mọlẹbi awọn to padanu ẹmi wọn sinu ikọlu idigunjale banki Ọffa lọdun 2018.
 
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹsan, ọdun 2024 ni ile ẹjọ gbe idajọ ododo naa kalẹ lori gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu idigunjale banki Ọffa ọhun.

Ẹgbẹ naa sọ pe lasiko ti iwadii n lọ lọwọ, awọn afurasi ti wọn ti wa gba idajọ wọn gbe oriṣiriṣi ẹri kalẹ.
 
Wọn ni lara awọn afurasi ọhun ni wọn kopa nibi ayẹyẹ igbeyawo ọmọ Saraki, ti wọn si wọ aṣọ ẹbi.
 
Bakan naa ni wọn tun sọ pe lara awọn mọto ti wọn gbe lọ digunjale ni wọn lo jẹ ọkan lara awọn mọto aarẹ ile igbimọ aṣofin tẹlẹri naa.
 
Ninu atẹjade ti alakoso eto iroyin fun ẹgbẹ YDC, Abdulbaki Kure gbe jade niluu Ilọrin, o ni inu awọn dun lori idajọ ododo to waye naa, ti Gomina AbdulRazaq ko ṣojusaaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI