Ẹgbẹ́ gómìnà Nàìjíríà bá àwọn èèyàn Niger, Borno, Yobe kẹ́dùn ìjàmbá omíyalé àti iná - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 12, 2024

Ẹgbẹ́ gómìnà Nàìjíríà bá àwọn èèyàn Niger, Borno, Yobe kẹ́dùn ìjàmbá omíyalé àti iná


Ẹgbẹ awọn gomina lorileede Naijiria ti ba ijọba ati awọn araalu Niger, Borno ati Yobe kẹdun lori ijamba omiyale, agbara ya ṣọọbu to waye laipẹ yii.

Ijamba ọhun ni iroyin fi to wa leti pe bi ẹmi ati awọn ohun ọsin ṣe ṣofo, bẹẹ ni ọpọ dukia naa tun dohun igbagbe.

Nipinlẹ Niger, eeyan mejidinlaadọta lo ba iṣẹlẹ ijamba ina lọ sọrun alakeji, to si tun pa ẹgbẹẹgbẹrun ohun ọsin danu.

Tanka agbepo ni wọn lo ṣubu lulẹ lojiji lopopona Bida Agaie si Lapai, to si gbina loju ẹsẹ.

Ẹgbẹ gomina Naijiria gbadura ki Ọlọrun tẹ awọn to padanu ẹmi wọn safẹfẹ rere, bẹẹ ni wọn tun gbadura ki Ọlọrun tu mọlẹbi wọn ninu.

Bakan naa ni wọn tun jẹ ko di mimọ pe awọn arinrin-ajo nilo lati maa mu aabo ẹmi lọkunkundun ni gbogbo igba.

Nigba ti wọn n ba awọn ara Borno ati Yobe kẹdun, ẹgbẹ NGF sọ pe adanu nla niṣẹlẹ omiyale to sọ ọpọ eeyan di alainile lori jẹ.

Awọn agbegbe kan niluu Maiduguri ati Jere nipinlẹ Borno ati nipinlẹ Yobe.

Bakan naa ni wọn gbe oriyin fun bi ijọba apapọ ṣe dide si iṣẹlẹ pajawiri naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI