Ẹniọla Mariam Bọlaji, ọmọ bibi ipinlẹ Kwara lo ti fi itan tuntun balẹ fun ilẹ Afrika, paapaa orileede Naijiria pẹlu bo ṣe gba aami ẹyẹ Paralympic ninu idije ere idaraya Badminton lagbaye.
Eyii ko tii ṣẹlẹ ri ninu itan latigba ti wọn ti bẹrẹ ere idaraya Badminton lagbaye, Ẹniọla ni yoo jẹ ẹni akọkọ ti yoo gba aami ẹyẹ naa nilẹ adulawọ.
Fun awọn to ba mọ idije ọhun daadaa, laipẹ yii ni wọn gbe Ẹniọla sipo keji lagbaye ninu awọn ti mọ nipa ere idaraya Badminton daadaa.
Ẹniọla to wa nipo keji lagbaye lo fi ẹyin akẹgbẹ rẹ lati orileede Ukraine, Kozyna Oksana lelẹ pẹlu aami ayo mọkanlelogun si mẹsan ninu ifigagbaga ti awọn obinrin, iyẹn Women Single SL3 to n lọ lọwọ ni Paris.
Ju gbogbo rẹ lọ, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ba Ẹniọla yọ, to si gbe oṣuba kare fun un gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọdọ to n gbe ogo ipinlẹ Kwara ga kaakiri agbaye.
Gomina AbdulRazaq ninu ọrọ rẹ sọ pe aṣeyọri Ẹniọla jẹyọ lati ara titẹpa mọṣẹ, akikanju, ipinnu rere ati ṣiṣe amulo anfaani perete to gba iwaju rẹ kọja si rere.
Bakan naa ni gomina tun sọ pe ipo ipenija ara ti Ẹniọla wa fi han pe ko ro ara rẹ pin, ati pe o ni igboya lati fi itan tuntun balẹ si daadaa lati gbe ogo Naijiria ga.
No comments:
Post a Comment