Ẹ mu ọrọ omiyale lọkunkundun - Ijọba Kwara pariwo sita f'araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, September 19, 2024

Ẹ mu ọrọ omiyale lọkunkundun - Ijọba Kwara pariwo sita f'araalu


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gba awọn araalu lamọran lati mu ọrọ omiyale ati agbara ojo lọkunkundun.
 
Ijọba sọ pe oriṣiriṣi ọrọ ikilọ lo ti wa lati ọdọ awọn ajọ to mọ nipa oju ọjọ, to si ni awọn araalu ni lati gbọ ikilọ lati dẹkun omiyale ati agbara ya ṣọọbu.

Ninu atẹjade ti kọmiṣanna feto ikansira-ẹni, Bọla Olukoju fi sita, o ṣalaye pe awọn ileeṣẹ ati ajọ loriṣiriṣi ni wọn ti gbe ọrọ ikilọ jade nipa ayipada oju ọjọ nipa omiyale.

Bakan naa lo sọ pe awọn idanilẹkọọ ati ilanilọyẹ ti n lọ kaakiri nipa bi awọn araalu ṣe le dẹkun ijamba omiyale lagbebe wọn, ati pe wọn nilo lati tẹle awọn idanilẹkọọ ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI