Ẹ fọkànbalẹ̀, àwọn àṣeyọrí àkànṣe iṣẹ́ ìdàgbàsókè wa yóò fọhùn fẹ́gbẹ́ APC nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ - AbdulRazaq fọkàn àwọn olùdíje balẹ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, September 20, 2024

Ẹ fọkànbalẹ̀, àwọn àṣeyọrí àkànṣe iṣẹ́ ìdàgbàsókè wa yóò fọhùn fẹ́gbẹ́ APC nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ - AbdulRazaq fọkàn àwọn olùdíje balẹ̀


Bi eto idibo ijọba ibilẹ kaakiri orileede Naijiria ṣe sunmọ etile, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti fọkan gbogbo awọn oludije sipo oṣelu lawọn ijọba ibilẹ kaakiri balẹ.

Gomina AbdulRazaq sọ pe awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke toun ti ṣe gẹgẹ bii gomina yoo fọhun fun awọn oludije lẹgbẹ APC.

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan ni eto idibo ijọba ibilẹ yoo waye kaakiri orileede Naijiria, ti ko si yọ ipinlẹ Kwara silẹ.

Lasiko to n ṣe ipade pẹlu awọn oludije mẹrindinlogun sipo alaga kansu niluu Ilọrin, Gomina AbdulRazaq ni oun nigbagbọ pe awọn araalu yoo dibo fun awọn oludije lẹgbẹ APC.

O ni awọn ipa rere ati aṣeyọri ninu akanṣe iṣẹ idagbasoke ati ilọsiwaju ipinlẹ Kwara yoo ṣe anfaani pupọ, nitori pe araalu nigbagbọ ninu APC.

Bakan naa ni gomina gba awọn oludije sipo alaga kansu naa lamọran lati jẹ aṣoju rere fẹgbẹ APC lasiko ati lẹyin eto idibo.

Gomina AbdulRazaq ni ẹnikẹni ninu wọn ko gbọdọ mu eto idibo naa ni booba-o-pa, booba-o-bu-lẹsẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI